Àwọn ànfààní tó wà nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn tàbí gbéborùn ṣíṣe

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ka sọrọ eeyan lẹyin tabi ka ṣe eke nipa wọn ko le ma waye.
Ko si awujọ naa ti ẹnikan ko ti ni i sọrọ nipa ẹnikeji rẹ lẹyin. O le jẹ nipa iwa ti ẹni ti wọn n sọrọ rẹ lẹyin naa ni lọwọ, tabi iru aṣọ to maa n wọ, iru ile to ti wa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bo si tilẹ jẹ pe iwa buruku ni ọpọ eeyan ka sisọ ọrọ eeyan lẹyin si, awọn onwoye iwa ẹda kan fidi rẹ mulẹ pe, ki i ṣe iwa aburu bẹẹ naa.
Wọn ṣalaye pe iwadii fi han pe awọn eeyan ti ọrọ ẹyin sọ di ọrẹ timọtimọ, iyẹn ọrẹ alajọsọ, ki i ri ọrọ ẹlomi-in ti wọn n sọ lẹyin bii nnkan buruku.
Wọn ni yoo mu ki irori wọn ṣọkan, yoo si tun da wọn lara ya.
Ṣugbọn ninu ẹkọ ẹsin ati ẹkọ iwa ọmọluabi, iwa buruku gbaa ni ọrọ ẹyin tabi ṣiṣe eke nipa ẹnikeji wa.
Wọnyii ni awọn anfaani ti awọn onimọ nipa iṣe ẹda, ka silẹ nipa sisọ ọrọ ọlọrọ lẹyin.
Wọ̀nyí ni àwọn àǹfààní tí àwọn onímọ̀ nípa ìṣe ẹ̀dá, kà sílẹ̀ nípa sísọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ lẹ́yìn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìròyìn tuntun
Dokita Nicole Hagen Hess, to kẹkọọ nipa irori eeyan ni Washington State University l'America, sọ pe bi awọn kan ba n sọrọ ẹlomi-in lẹyin, wọn n fun ara wọn ni iroyin tuntun nipa ẹni naa ni.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe ohun ti ẹni akọkọ ko mọ nipa ẹni naa tẹlẹ, ikeji rẹ ti wọn n jọ n ṣeke yii yoo sọ fun un.
" Bi o ba n sọrọ nipa ẹnikan, tabi iru aṣọ to wọ, tabi nnkan to ṣe, koda bi ẹni naa ba wa niwaju rẹ bayii, ṣugbọn ti ko gbọ ohun ti o n sọ, eke naa ṣi ni, ọrọ ẹyin ni."
Idi ti awọn eeyan ko ṣe le ṣalai sọrọ ẹyin ni awọn oluwadii ko ti i ri, bi wọn ṣe n wa a to.
Ó máa ń jẹ́ kí àṣírí ìkọ̀kọ̀ tú
Ọjọgbọn Robin Dunbar, onimọ nipa iwa ẹda, ṣalaye pe awọn inaki to da bi eeyan lo maa n sọrọ ẹyin ju, iṣesi naa si ni awa eeyan kọ pẹluu.
O ṣalaye pe lẹyin ọrọ ẹyin nipa ẹnikan, ija le de laaarin awọn to n sọrọ rẹ naa.
Ọjọgbọn Dunbar ni ẹni ti wọn sọrọ nipa rẹ yoo waa pada mọ gbogbo ohun ti wọn wi nipa rẹ.
Lẹyin eyi ni yoo si mọ bi oun ṣe jẹ lọkan awọn èké ọhun, yoo mọ bi yoo ṣe sa fun wọn.
Iṣẹ iwadii kan ti wọn ṣe ni Dartmouth University, l'America, ni 2021,fi han pe ibaṣepọ awọn eke yoo maa rinlẹ niwọn igba ti wọn ba ṣi jọ wa pọ.
Ó wúlò fún ìkìlọ̀
Dr Nicole Hagen Hess, ṣalaye ninu ọrọ rẹ pe, eke ṣiṣe le ran ẹnikeji lọwọ.
Bi apẹẹrẹ, laaarin awọn obinrin, o ni bi obinrin kan ba ṣẹṣẹ bẹrẹ si i fẹ ọkunrin tuntun, to si jẹ pe iwa buruku kan wa lọwọ ọkunrin naa ṣugbọn ti obinrin yii ko mọ.
Dr Nicole Hagen Hess sọ pe obinrin to ti lugbadi iwakiwa naa lọdọ ọkunrin yii le ṣeke fun eyi to ṣẹṣẹ fẹẹ ko si panpẹ ọkunrin naa.
Iru ọrọ ẹyin bi eyi yoo ṣe anfaani fun obinrin to gbọ aṣiri, yoo si mu ko yẹra fun ọkunrin naa, nigba ti yoo sọ ọ di ọrẹ obinrin bii tiẹ to sọrọ ẹyin fun un.
Ìdárayá
Si awọn ẹlomiran, ọrọ ẹyin ki i ṣe ohun ti ko daa, ẹfẹ, awada ati idara ẹni lara ya ni wọn ka a si.
"Emi fẹran eke ṣiṣe to ba mu idaraẹni lara ya da ni." McKinney, ọmọbinrin kan to maa n sọrọ lori ayelujara lo sọ bẹẹ.
" Ki lo maa ṣẹlẹ ti mi o ba ri eke kankan ṣe lọjọ kan, niṣe lo maa da bii pe aye ti fẹẹ parẹ."
"Boya fun idaraya tabi ka fi so okun ọrẹ le danin-danin, eke ṣiṣe ati ka sọrọ eeyan lẹyin ti di apa kan iwa ẹda ti a ko le maa ṣe.
Dokita Hess lo sọ bẹẹ.
Ṣugbọn o, bi eeyan ba n ranti ọrọ awọn iwe mimọ, to si n huwa ọmọluabi, ko ni i lọwọ si sisọ ọrọ ọmọlakeji lẹyin lai daa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images














