Elémùré ti ìlú Emure Ekiti, Ọba Emmanuel Adebayo wàjà

Emmanuel Adebowale Adebayo

Oríṣun àwòrán, W.A. Adebayo

Ni Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu karun un, ọdun 2024 ni iroyin ipapopa ọba Emmanuel Adebowale Adebayo, Elemure tilu Emure Ekiti jade.

Ọdun 2008 ni ọba naa gori itẹ awọn baba nla rẹ, to si lo ọdun mẹrindinlogun lori ipo naa ki ọlọjọ to de lọsẹ to kọja.

Ọjọgbọn W.A. Adebayo to fidi iroyin naa mulẹ lorukọ awọn mọlẹbi ṣalaye pe ọba naa lo waja lẹyin aisan rampẹ, o si dagbere faye ni ilu Eko.

Ọba to waja naa lo ti figba kan ri jẹ kọmisọna ọlọpaa lawọn ipinlẹ bii Eko, Edo, ati Abuja.

Ọga agba ile isẹ ọlọpaa ni Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun ti kẹdun ipapoda ori ade ọhun.

Wọn bi Ọba Emmanuel Adebowale Adebayo Aminmin keta ti ilu Emure Ekiti sinu ẹbi ọmọba Ezekiel Kehinde Adebayo,

O bọ sori itẹ lẹyin ipapoda ọba Simeon to jẹ Aminmin keji ti ilu Emure Ekiti.

O lọ si ile ẹkọ St. Paul laarin ọdun 1955 si 1960, Isẹ Emure Grammar School lo lọ laarin ọdun 1963 si 1967 ati Ijẹbu ode lọdun 1968 si 1970.

Ile isẹ ọlọpaa lo fi bẹrẹ isẹ ṣiṣe ko to ni igbega lẹnu isẹ naa titi to fi de ipo kọmisọna ile isẹ ọlọpaa ko ti bọ sori apere ọba lọdun 2008 si 2024 ti ọlọjọ de.

Orisirisi ami ẹyẹ ni ori ade to waja naa ti gba ni ilu Emure ati ni ilẹ Najiria pẹlu awọn mii nilẹ Amerika.