Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin pẹ̀lú $498,100 ní Rivers

Oríṣun àwòrán, Chinyere Igwe
Dọkita Chinyere Igwe, ọmọ ile igbimọ aṣofin kekere ni ọwọ ti tẹ pẹlu ọpọlọpọ owo ni opopona Ana niluu Port Harcourt lowurọ Ọjọ Ẹti.
Igwe, ẹni to soju ẹkun ijọba Port Harcourt keji, to si tun jẹ ọkan lara awọn to ṣe ipolongo ibo fun oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Grace Iringe- Koko ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin, ni ọwọ tẹ Igwe ni igbati awọn ẹsọ alabo to fwa sisẹ pọ ajọ INEC n ṣe duro ki a yẹwo ni opopona Aba niluu Port Harcourt.
Lẹyin ti owo ọmọ ile igimọ aṣofin naa ni igbakeji ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa to n mujuto eto idibo nipinlẹ naa, AIG Abutu Yaro pasẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadi ati ifọrọwerọ lẹsẹkẹsẹ pẹlu Igwe.
A ri iwe bi wọn ṣe fẹ pin owo ninu ọkọ ayọkẹlẹ
Iringe-Koko tẹsiwaju pe awọn ọlọpaa tun ri iwe bi wọn ṣe fẹ pin owo naa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa
“Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti wọn ran lọ si ọfisi Ajọ INEC lọni, Ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun 2023, nigba ti wọn ṣe ayẹwo awọn ọkọ to n kọja loju opopona mu Chinyere Igwe, ọmọ ile igbimọ aṣofin to n soju Port Harcourt keji pẹlu owo toto ẹgbẹ lọna mejidinlẹẹdẹgbẹta owo dọla ninu apo kan ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.
“Bakan na ni a ri iwe bi wọn ṣe fẹ pin owo naa. Igbakeji ọga agba ọlọpaa lori eto idibo, Abutu Yaro ti pasẹ pe iwadi bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ.
“Ileeṣẹ ọlọpaa n pe awọn oludije ati awọn ẹgbẹ oṣelu lati tẹle ofin ati ilana ti Ajọ eleto idibo gbe kalẹ.”
Iringe-Koko, wa rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati lo anfani awọn ẹrọ ibanisọrọ ti ileeṣẹ pese lati pe akiyesi ti wọn ba kẹfin iwuwasi kan tabi ominran to lodi sofin ilu.”

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Rivers












