Àwọn onímọ̀ ṣàwárí 'ihò ìyọ̀ tó gùn jù láyé' nítòsí ìbì tí ìyàwó Lọti inú Bíbélì ti di iyọ̀

Obinrin kan n wo ọwọn iyọ ninu iho Malham Cave ni Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn amoye kan lorilẹede Isreal sọ pe awọn ti ṣawari iho inu apata to kun fun iyọ̀ ju lagbaye.

Awọn onimọ naa sọ pe iho ọhun wa nitosi ibi ti Bibeli sọ pe iyawo Lọọti di ọ̀wọ́n iyọ̀ si.

Àkọlé fídíò, ẹ̀fọ́ rírò jẹ́ alábárìn iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun

Lati bi ọdun meji ni wọn ti ṣe odiwọn iyọ to dipọ to iwọn kilomita mẹwa ninu iho Malham Cave naa, to doju kọ okun Dead Sea.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn onimọ naa sọ, o ṣeeṣe ki iho naa gun si bi òjò ba ṣe n rọ si.

Iyọ to duro ninu Malham cave

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹwẹ, lati nkan bi ọdun 1980 ni wọn ti ya apa ibikan sọtọ ninu iho naa to gun de ori-oke Sodom, to jẹ apata to gun julọ lorilẹede Israel.

Awari tuntun yii tayọ ọ̀kan to waye lọdun 2006 to ṣafihan iho iyọ Cave of the Three Nudes to wa ni Erekusu Qeshm lorilẹede Iran.

Onimọ n wo ọwọn iyọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images