AFCON 2019: Àmì ayò tí Nàíjíríà àti South Afrika gbá rèé

Oríṣun àwòrán, GIUSEPPE CACACE
Ikọ agbabọọlu orileede Naijiria Super Eagles ti gbewuro soju ikọ Bafana Bafana ti South Africa lati tẹsiwaju ninu idije Afcon 2019 to n waye ni Egypt.
Samuel Chukwueze lo kọkọ gba bọọlu wọnu awọn South Africa ni iṣẹju kẹtadinlọgbọn ifẹswọnsẹ naa ki South Africa to da goolu pada ni iṣẹju karundinlọgọrin.
Bongani Zungu lo fi ori kan bọọlu sawọn Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Khaled Desouki
William Troost Ekong lo de goolu lade fun Naijiria ni iṣẹju kọkandinlaadọrun.
Ni bayi Naijiria yoo koju Algeria tabi Ivory Coast ninu abala to kangun si aṣekagba idije naa.








