Buhari: N kò fi ìgbógun ti ìwà ìjẹkújẹ halẹ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni

Oríṣun àwòrán, EFCC
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣi olu ileeṣẹ tuntun fun ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ to rọ mọ iṣuna lorilẹede Naijiria, EFCC nilu Abuja.
Ninu ọrọ rẹ lasiko to fi n ṣe ifilọlẹ olu ileeṣẹ naa, Aarẹ Buhari ni, iṣejọba oun ko fi eto gbigbo-gun ti iwa ijẹkujẹ toun gunle, dunkoko mọ ẹnikẹni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aarẹ Buhari ni, ko si ani-ani lori ipinnu oun lati tubọ tẹra mọ gbigbo-gun ti iwa ijẹkujẹ.

Oríṣun àwòrán, EFCC
"Afojusun mi ni lati doju ija kọ iwa ijẹkujẹ lai wẹyin wo. Ohun ti iṣejọba mi n lepa ni lati daabo bo igbẹkẹle araalu. A ko wa lati fi eto igbogun ti iwa ibajẹ dun mọhuru-mọhuru mọ ẹnikẹni."

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ninu ọrọ tirẹ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ olu ileeṣẹ ajọ EFCC naa, olori ile aṣoju-ṣofin, Yakubu Dogara ni, asiko to lati mojuto igbayegbadun awọn oṣisẹ ajọ EFCC, a si gbọdọ mu ayipada ba gule-gule iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ EFCC, fun obitibiti owo to to biliọnu mẹrinlelogun naira, ti wọn fi kọ olu ileeṣẹ naa.








