Isẹlẹ Boko Haram: Eniyan 17 ku ninu ijamba ado oloro ni Konduga

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn eniyan meji ti wọn so ado oloro mọ'ra ti ṣe iku pa eniyan mẹtadinlogun ti awọn eniyan miran ti wọn to aadọta si farapa yanayana ni ilu Konduga nipinlẹ Borno.
Ẹnikẹni ko tii f'ọwọ sọ'ya pe awọnlo ṣokunfa iṣẹlẹ ibi yii ṣugbon ẹnu nkun awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti wọn tii n gbogun ti orilẹede Naijiria lati ọdun 2013.
Akọroyin BBC nilu Abuja, Is'haq Khalid wipe awọn afurasi ọmọ Boko Haram ti wọn so ado oloro mọra ṣadeede wọ inu ọja ẹja nla kan ni oru ana nilu Konduga, lagbegbe Maiduguri.
Ajọ to n sakoso eto iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Borno sọ pe ẹmi mọkandinlogun lo ba ijamba yii lọ pẹlu awọn apaniyan mejeeji to ṣ'okunfa rẹ.
O ṣalaye wipe ogunlọgọ awọn ti o fara kaaṣa ninu ijamba yii ti wa ni ile iwosan ijọba fun itọju.

Bi o tilẹ jẹ pe orilẹede Naijiria ni ilọsiwaju ninu ija awọn ọmọ ologun pẹlu ẹgbẹ Boko Haram, awọn agbesunmọmi yii ṣii n ṣiṣẹ ikọlu pẹlu ado oloro ati awọn ipaniyan pẹlu ibon loore-koore ni ariwa-iwọ oorun orilẹede Naijiria, ni apa ibi ti o ti sunmọ orilẹede Niger, Cameroon ati Chad.
Ni ọsẹ yi ni ileeṣẹ ologun orileede Naijiria kede ẹbun miliọnu mẹta naira fun ẹnikẹni to ba ni iroyin tabi ifitonileti kankan to le se'ranlọwọ lati ri olori igun kan ninu ẹgbẹ Boko Haram, Abubakar Shekau ti wọn n wa.








