Buhari ṣ'eto igbimọ fun abẹwo awọn ipinlẹ ti o ni ikọlu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣ'eto igbimọ miiran ti yoo lọ ṣe abẹwo si gbogbo awọn agbegbe ti o ni ikọlu nipasẹ ija laaarin awọn agbẹ ati darandaran fulani ni orilẹ-ede Naijiria.
Abẹwo naa, gẹgẹbi Gomina Mohammed Abubakar ti ipinlẹ Bauchi ṣe sọ, yoo jẹ ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣ'ada lori awọn ọna ati "ṣe atunṣe ati dẹkun irora awọn eniyan ni awọn agbegbe naa".
Ọgbẹni Abubakar, ti o ba awọn oniroyin sọrọ nilu Abuja lẹyin ipade igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) sọ wipe igbakeji aarẹ, ọjọgbọn Yemi Osinbajo ni yoo jẹ adari igbimọ naa.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
O sọ pe igbimọ Osinbajo ti Aarẹ Buhari ti gbe kalẹ ni yoo jẹ afikun si igbimọ alakoso ti o ṣaju rẹ tẹlẹ, eyi ti Gomina ti Ebonyi, David Umahi n ṣ'akoso rẹ.
O sọ siwaju sii wipe Ọjọgbọn Osinbajo ti ṣe agbekalẹ ipinnu ati ijabọ fun igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) nibi it gbogbo awọn gomina ipinlẹ ati awọn minisita peju-pesẹ si.








