Lórí ìrìnàjò Buhari sí London: Garba Shehu ni ààrẹ lè ṣe ìjọba níbikíbi

Amofin agba Femi Falana ati amofin Mike Ozhekome wa lara awọn onimọ to ti bẹnu atẹ lu bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe gbori le ilu London lai sọ idi ti oun fi n lọ fun Ile Igbimọ Aṣofin.
Ṣugbọn agbẹnusọ ileeṣẹ aarẹ, Garba Shehu ti ni tiwọn ni wọn n wi. O ni aarẹ lẹ ṣe ijọba nibikibi, ati wipe ko ni lati fi to awọn aṣofin leti ti o ba fẹ lọ ṣẹ abẹwẹ ranpe nilu ọba.
Láti igba ti Buhari ti de ori aleefa, iroyin fi han wipe, o ti lo ọdun kan, ati ọjọ mọkaindinlogoji lẹyin odi. Ninu eyi, o lo igba ọjọ ole mẹtadinlogun ni Ilẹ Gẹẹsi nibi to ti lọ gba itọju.

Oríṣun àwòrán, AFP
Falana ni iwe ofin orilẹede Naijiria sọ wipe ti aarẹ ba fẹ rin irinajọ lọ ẹyin odi, ọ gbọdọ fi to awọn aṣofin leti. O ni ọjọ mẹwaa pọju fun aarẹ lati fi aga rẹ silẹ lọ lai fa ijọba le ọwọ ẹni kankan.
Amofin naa ni, "Bo ti wa di pe aarẹ lọ irinajo laisọ oun ti o fẹ lọ ṣe nibẹ, ko ṣeeṣe fun un lati ṣe alaga igbimọ to n dari ilu. Ṣe ni o yẹ ki o kọ iwe lati fi to Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba, ati abẹnugan Ile Igbimọ Aṣoju-ṣofin leti,"
Bẹẹ gẹgẹ ni amofin Ozekhome naa ṣọ.
O ni kii ṣe pe irinajo aarẹ lodi sofin nikan, ko fi iwa rere han. Ozekhome ni, kilode ti aarẹ ṣe maa n fi awọn irinajo ti tẹlẹ to awọn aṣofin leti ti yoo si gbe ijọba le Osinbajo lọwọ?

Oríṣun àwòrán, Chronicle.ng
Ninu esi rẹ, Garba Shehu ni aarẹ le lo agbara lati ṣelu nibi to ba wu ko lọ. O ni koda, aarẹ le lo to ọjọ mọkanlelogun ni ẹyin odi lai fi to awọn aṣofin leti.












