Òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́: A ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì fún ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Google
Awọn osisẹ ijọba ni ipinlẹ Ọyọ ti gunle iyansẹlodi oni ikilo ọlọjọ meta lati beere fun ohun ti wọn fẹ lọwọ ijọba.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ to n duna-dura lorukọ awọn oṣiṣẹ, Public Service Joint Negotiation Council, fi sita lati ọwọ Akinfenwa Olabọde, ṣalaye wi pe ijọba kọ lati dahun si awọn ẹtọ ti awọn beere fun ninu iwe ti awọn kọ si ijọba ni Ọjọ Keje, Osu Kini, ọdun 2019.
Ninu ọrọ wọn, Ọjọru ni iyansẹlodi naa yoo beere ti ijọba ko ba wa wọrọkọ fi sada lori awọn ohun ti awọn osisẹ ijọba naa n beere fun lẹyin ikilọ ọlọjọ meje ti awọn fun wọn, to si pari ni Ọjọ Isẹgun, ọsẹ yii.
Ẹgbẹ naa wa parọwa si gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiola Ajimobi lati dahun si ọrọ to jọmọ igbaye gbadun awọn osisẹ ni ipinlẹ naa.









