Ìjàmbá Ọkọ̀: Ọkọ̀ aképo dànù lópòópónà Eko sí Ibadan

Ọkọ̀ aképo dànù lópòópónà Eko sí Ibadan
Àkọlé àwòrán, Ọkọ̀ aképo dànù lópòópónà Eko sí Ibadan

Ó ń sẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan níbi tí Ọkọ̀ aképo kan ti dànù.

Lákòókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, a gbọ́ pé ọkọ̀ náà kún fọ́fọ́ fún epo bẹ́ntiróòlù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Ọkọ̀ náà kún fọ́fọ́ fún epo bẹ́ntiróòlù
Àkọlé àwòrán, Ọkọ̀ náà kún fọ́fọ́ fún epo bẹ́ntiróòlù

Ọkọ̀ yìí tí dẹ́bùú sójú ọ̀nà tó sì ti dí apá kan ọ̀nà náà.

àwọn ènìyàn ṣe ń fi igbá àti kẹ́ẹ̀gì bu epò láti inù ọkọ̀ náà.
Àkọlé àwòrán, àwọn ènìyàn ṣe ń fi igbá àti kẹ́ẹ̀gì bu epò láti inù ọkọ̀ náà.

Fọ́fọ́ ní ibi ìṣllẹ̀ yìí kún fún èrò gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe ń fi igbá àti kẹ́ẹ̀gì bu epò láti inù ọkọ̀ náà.

àwọn ènìyàn ń sá dìgbà dìgbà láti bu epo.
Àkọlé àwòrán, àwọn ènìyàn ń sá dìgbà dìgbà láti bu epo.

Lójú àwọn Ọlọ́pàá àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ni àwọn ènìyàn ti ń sá dìgbà dìgbà láti bu epo.

Àkọlé fídíò, 'Àwa oní Tíátà kìí dúró nílé, àwọn ọmọ wa nílò wa'