Kọmísọ́nà ọlọ́ọ̀pá dá ọ̀gá ọlọ́ọ̀pá dúró lẹ́nu isẹ́

Oríṣun àwòrán, Police forcee/twitter
Ile isẹ ọlọọpa ni ilu Eko ti kọ iwee lọ gbe ile rẹ fun ọga ọlọọpa fun ẹka to n koju ẹgbẹ okunkun ni ilu Eko, Godwin Agbegbe pẹlu ẹsun wi pe wọn n wu iwa ibajẹ ati ajẹbanu ni awujọ.
Awọn osisẹ to n sisẹ labẹ Agbegbe naa faragba ninu rẹ nitori ajọ ọlọpa pasẹ fun wọn lati wa ni olu ile isẹ wọn ni Abuja ki wọn le fi wọn si ibo miran lati se isẹ .
Ọlọpa to ba Iwe Iroyin Punch sọ ọrọ wi pe ọpọ igba ni wọn ti fi ẹsun kan ọga ọlọpa naa ati awọn ikọ rẹ wi pe wọn n se asemase, koto di pe ọga ọlọpa, Edgal Imohimi gbe igbese lati le awọn ọlpa naa.
Agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọpa ni ilu Eko, CSP Chike Otti fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn da ọga ọlọọpa naa duro lẹnu isẹ.








