Russia 2018; Àwọn ọmọ ilẹ́ Afrika tó ń gbábọ́ọ́lù fún orílẹ̀èdè míràn

Èyí ni àkójọpọ̀ orúkọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Afrikasùgbọ́n wọ́n ń gbá bọ́ọ́lù fún orílẹ̀èdè míràn.

Ife ẹ́yẹ àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìdíje ife ẹ́yẹ àgbáyé yóò wáyé lóṣù kẹfà lórílẹ̀èdè Russia

Delle Alli

Delle Alii

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2015 ni Delle Alii bẹrẹ si ni gba bọọlu pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu agba fun ilẹ England.

Ọmọkunrin to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham Hotspur naa jẹ ọm bibi orilẹede Naijiria, amọ orilẹede England ni oun gba bọọlu fun.

Ọdun 2015 ni Delle Alii bẹrẹ si ni gba bọọlu pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu agba fun ilẹ England.

Kylian Mbappe

Kylian Mbappe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mbappe n gba bọọlu fun ikọ Paris Saint German ti orilẹede ti wọn bii si

Ọmọ ilẹ Cameroon ni baba Mbappe, ti iya rẹ si jẹ ọm ilẹ Algeria, amọ ilẹ faranse ni wọn ti bi Mbappe.

Lati kekere ni Mbappe, ọmọ ọdun mọkandinlogun naa ti n gba bọọlu fun ilẹ Faranse, ko to di wipe owa gbajugbaja pẹlu ẹgbẹ agbabọlu ilẹ Faranse.

O si tun n gba bọọlu fun ikọ Paris Saint German ti orilẹede ti wọn bii si.

Ross Barkley

Ross Barkley

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Baba rẹ, Peter Effanga jẹ ọmọ bibi ilẹ Naijiria, amọ iya rẹ jẹ ọmọ Ilẹ Gẹẹsi

Ross Barkley to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Everton ati ilẹ England,ni orukọ rẹ ko jọ mọ orukọ orilẹede Nigeria, amọ orilẹede Naijiria lo ti san wa.

Baba rẹ, Peter Effanga jẹ ọmọ bibi ilẹ Naijiria, amọ iya rẹ jẹ ọmọ Ilẹ Gẹẹsi, oun losi mu ki arakunrin naa o ma gba bọọlu fun Ilẹ Gẹẹsi.

David Alaba

David Alaba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Alaba ni wọn bi si Vienna, ti baba rẹ jẹ ọmọ Naijiria

Nigba ti Bayern Munich gba Ife Ẹyẹ Idije Uefa Champions League lọdun 2013, David Alaba ni ọpọ eniyan ri to so asia orilẹede Naijira ati ti Austria mọra lẹyin ti wọn gba Ife naa.

Alaba ni wọn bi si Vienna, ti baba rẹ jẹ ọmọ Naijiria, olorin takasufe, amọ ti iya rẹ jẹ nọọsi alabẹrẹ lati ilẹ Philipine.José Bosingwa

José Bosingwa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, José Bosingwa jẹ agbabọọlu to lamilaaka

José Bosingwa to n gba bọọlu fun ọwọ ẹyin jẹ ọmọ bibi ilẹ DR Congo, amọ ilẹ Portugal lo n gba bọọlu fun.

Bosingwa jẹ agbabọọlu to lamilaaka, ti awọn eniyan bọwọfun lori papa.

Marcel Desailly

Marcel Desailly

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Desailly to jẹ gbajugbaja ni awọn obi rẹ mu kuro ni orilẹede Ghana nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrin

Marcel Desailly to n gba bọọlu gẹgẹbi adilemu ọwọ ẹyin, ninu iwe to kọ nipa ara rẹ sọ wi pe, inu oun dun lati ma a gba bọọlu fun ilẹ Faranse ti oun ko si gba bọọlu fun orilẹede Ghana, to jẹ ibi ti wọn bi oun si.

Desailly to jẹ gbajugbaja ni awọn obi rẹ mu kuro ni orilẹede Ghana nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrin, lati igba naa lo ti n gba bọọlu fun ilẹ Faranse.

Oguchi Onyewu

Oguchi Onyewu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni bayii, Onyewu ti da ọmọ ilẹ Amerika

Ọmọ bibi ilẹ Naijiria ni Onyewu, orukọ abisọ rẹ si n jẹ Oguchialu Chijioke Onyewu, ti wọn bi lọdun 1982, sugbọn awọn obi rẹ kuro ni Naijiria losi orilẹede Amẹrika lati lọ kawe.

Ni bayii, to ti da ọmọ ilẹ Amerika, Onyewu fun igba akọkọ kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ laarin orilẹede Amerika ati Panama.

Tiago Ilori

Tiago Ilori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilori yan orilẹede Portugal laayo lati gba bọọlu fun gẹgẹbi ọmọ ilẹ naa

Tiago Ilori to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ni wọn bi ni Ilẹ Gẹẹsi, amọ ọmọ ilẹ adulawọ ni baba rẹ, ti iya rẹ si jẹ ọmọ Ilẹ Portugal.

Ilori yan orilẹede Portugal laayo lati gba bọọlu fun gẹgẹbi ọmọ ilẹ naa.

Wilfried Zaha

Wilfried Zaha

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wilfried Zaha jẹ ọmọ bibi ilu Abidgan, ni orilẹede Cote d'Ivoire

Agbabọọlu igun ọwọ osi naa jẹ ọmọ bibi ilu Abidgan, ni orilẹede Cote d’Ivoire, sugbọn Ilẹ Gẹẹsi ni oun gba bọọlu fun.

Christian Benteke

Christian Benteke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Christian Benteke tun gba fun Liverpool

Benteke to jẹ agbabọọlu ọwọ iwaju ni wọn bi si ilu Kanshasa, lorilẹede DR Congo, amọ orilẹede Belgium ni oun gba bọọlu fun gẹgẹbi ilẹ ti o ti wa.

Agbabọọlu naa to tun gba fun Liverpool, ni ọpọ eniyan foju si lara wipe yoo pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ laarin Belgium ati orilẹede miran.