Ilé Aṣòfin: Omo-Agege lee wọlé títí ìdájọ́ kòtẹ́lọ́rùn

Oríṣun àwòrán, @Omo-Agege
Ile Aṣofin Agba l'Abuja sọ pe ohun ti ṣetan lati tẹ̀lé idajọ ileẹjọ giga t'ijọba apapọ lori ọrọ sẹnẹtọ Ovie Omo-Agege .
Eleyi lo mu ki ile asofin gbẹ́sẹ̀ kúrò lóri òfin tó fi de Omo-Agege, tó lè padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
Alaga igbimọ ile to n ri si ọrọ iroyin ati ipolongo Sẹnẹtọ Sabi Abdullahi, lo sọrọ naa di mimọ l'Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O fi kun ọrọ rẹ pe, ile ko ni di sẹnẹtọ naa lọwọ lati pada s'ẹnu iṣẹ rẹ.
Sẹnẹtọ Abdullahi wipe, ile ti ṣetan lati duro de idajọ ileẹjọ ko tẹmilọrun, ki ile to gbe igbesẹ miran.








