Boxing Day Derby: Arsenal rọ̀jò ẹ̀sẹ́ lé Chelsea lórí, 3-1 ló parí sí ní Emirates

Lacazette

Oríṣun àwòrán, Reuters

Xhaka ati Bukayọ Saka wa lara awọn agbabọọlu to gbimọran pọ ṣe Chelsea ṣakaṣaka lọjọ Boxing Day.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye ni papa isere Arsenal ni Emirates, apọnkun iya goolu mẹta sookan ni Arsenal fi jẹ ikọ Frank Lampard.

Goolu akọkọ Granit Xhaka ni saa bọọlu ọdun yi ni Arsenal fi ṣe Ade lori goolu meji ni abala kini idije naa.

Lati ibẹrẹ idije naa ni Arsenal ko ti ba Chelsea rẹrin rara ti wọn si n dẹgun soju ile Chelsea titi ti wọn fi jẹ goolu akọkọ lati ọwọ Lacazette ni iṣju marundinlogoji ifẹsẹwọns naa.

Bi eeyan ko ba mọ awọn agbabọọlu Arsenal tẹlẹ ri yoo ro wi pe ikọ mi ni Mikel Arteta ko si ori papa pẹlu bi wọn ti ṣe n ṣigun ba awọn alatako wọn.

Ni abala kejii ifẹsẹwọnsẹ naa, Bukayo Saka jẹ aramọnda goolu lati fi sọ di mẹta sodo.

Anfaani ti Chelsea ri ko pọ ṣugbọn Tammy Abraham rapala jẹ goolu kan ti Jorghinho si padanu gbe silẹ gba sile ti wọn ri.

Saka scores

Oríṣun àwòrán, Reuters

Pẹlu bi nkan ti ṣe duro bayi, Arsenal wa ni ipo Kẹrinla lori afara liigi.

Ti wọn ba fidirẹmi Chelsea yoo bọ si ipo kẹfa ti Aston Villa yoo si lewaju wọn ni ipo kaarun.