Payet: A o kọ kọrúkọ wa sínú ìwé ìtàn pẹ̀lú ife ẹ̀yẹ Europa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Balogun ikọ agbabọọlu Marseille, Dimitri Payet ti rọ awọn akẹgbẹ rẹ lati ja fitafita lati bori ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Europa l'ọjọru.
Payet fẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Marseille kọ orukọ ara wọn sinu iwe itan nigbati wọn ba koju ikọ Atletico Madrid ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Igba akọkọ re ti ikọ Marseille yoo de ipele aṣekagba ninu idije ere bọọlu nilẹ alawọ funfun lati ọdun 2005.
Marseile yoo koju Atletico Madrid to ti gba ife ẹye Europa naa ni ọdun 2010 ati 2012.
Amọṣa wọn fidi rẹmi ninu aṣekagba idije UEFA Champions lẹmeji lati ọdun 2012 titi di akoko yii.
Ẹwẹ, olukọ ikọ Atletico, Diego Simeone, ko ni si lori papa lasiko ifẹsẹwọnsẹ pẹlu bi alamojuto ifẹsẹwọnsẹ laarin ikọ naa ati Arsenal fi koju ni ipele to kangun si aṣekagba.








