Arẹgbẹsọla: Osisẹ lo jiya isoro ọrọ aje to dagun julọ

Opopona osisẹ ni ilu Osogbo

Oríṣun àwòrán, @IleowoKikiowo

Àkọlé àwòrán, 'Bi ijọba ana lorilẹede Naijiria se se asuwọn ilu basubasu lasiko to fi wa nipo lo sakoba fun eto ọrọ aje orilẹede Naijiria'

Awọn osisẹ lo fara kaasa wahala ọrọ aje to dagun lorilẹede Naijiria julọ.

Gomina ipinlẹ Ọsun lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, Rauf Arẹgbẹsọla lo sọ ọrọ yii lasiko to fi n si opopona onibeji kan to fi sọ'ri awọn osisẹ ipinlẹ naa.

Gomina Arẹgbẹsọla ni lootọ ni wi pe awọn osisẹ ni ori n ta julọ pẹlu bi ọrọ aje se n dagun lorilẹede Naijiria, amọsa ijọba ana, gẹgẹbi o se sọ, labẹ isakoso ẹgbẹ oselu PDP leku ẹda to daa silẹ.

Arẹgbẹsọla ni bi ijọba ana lorilẹede Naijiria se se asuwọn ilu basubasu lasiko to fi wa nipo lo sakoba fun eto aje orilẹede Naijiria eleyi to si jọ wi pe awọn osisẹ ni atubọtan ọrọ naa si ba lara julọ.

Awọn osisẹfẹyinti n se iwọde nipinlẹ Ọsun

Oríṣun àwòrán, Olu Alebiosu

Àkọlé àwòrán, Airi owo osu gba lagbape fun awọn osisẹ kan ni ipinlẹ Ọsun da ọpọ awuyewuye silẹ

"Ẹgbẹ oselu PDP sefilọlẹ ileegbọnsẹ, ilee itun irun se ati kọngadẹrọ lasiko to fi se ijọba ni ipinlẹ yii.

Pupọ awọn isẹ ti wọn si se ifilọlẹ rẹ yii ni ko wulo fun araalu sugbọn opopona yii yoo mu ọrọ aje burẹkẹ sii fun araalu."

Ni ipinlẹ ọsun o ti le ni ọdun meji bayii ti pupọ lara awọn osisẹ ijọba ko ti ri owo osu wọn gba lagbape eleyi to si ti fa oniruuru awuyewuye nibẹ.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Amọsa, Gomina ipinlẹ Ọsun ni ijọba oun ko sai mọ riri ifarajin awọn osisẹ nibẹ.

O ni ara fifi imoore han fun ifarada awọn osisẹ lo sokunfa bii ijọba oun se fi opopona onibeji tuntun naa sọ ori awọn osisẹ nipinlẹ naa.

"Ipinnu wa lati fi ọna yii sọ ori awọn osisẹ ko yẹ lẹyin ifọkansin, ipamọra ati ifarada wọn.

Mo gb'osuba fun awọn osisẹ nitori awọn gan an ni eegun to n bẹ lẹyin oro ti oro fi n ke fun ijọba yii ti a si fi lee mu ileri wa sẹ fun awọn araalu."

Kini ẹgbẹ oselu PDP sọ si ọrọ yii?

Amọsa nigba ti yoo fesi, igbakeji alukoro fun ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Diran Ọdẹyẹmi ni ariwo lasan ni gomina Aregbẹsọla n pa ati wi pe n kan to ku diẹ kaato ni fun ijọba APC ni ipinlẹ Ọsun lati maa di ẹbi 'aisede rẹ nijọba' lẹyin ti o ti lo ọdun mẹjọ nipo ru ẹgbẹ oselu PDP.

Ọlọpa n le awọn oluwọde ni ipinlẹ Ọsun

Oríṣun àwòrán, Olu Alebiosu

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ oselu PDP ni obitibiti gbese ni ijọba APC ti jẹ silẹ ni ipinlẹ Ọsun

"Biliọnu kan naira ni ẹgbẹ oselu PDP ti Arẹgbẹsọla n di ẹbi ru yii pa si asuwọn ipinlẹ Ọsun; sugbọn ko si ẹni to lee sọ ni pato bayii iye obitibiti gbese ti ipinlẹ Ọsun jẹ eleyii ti ko see sakawe pẹlu awọn isẹ to wa nilẹ."

Ọgbẹni Diran Ọdẹyẹmi salaye siwaju sii wipe gomina to sejọba lasiko ti o n sọ ọrọ rẹ yii gan an ti darapọ mọ ẹgbẹ oselu APC ti wọn si fi ilu ati ifọn gba a wọle gẹgẹ bii "odu nla lati ẹgbẹ oselu PDP".

Opopona onibusọ mẹta o din diẹ naa gba agbegbe Olaiya,Odi-Olowo,Ita-Olookan ni ilu Osogbo kọja.