Òkùnkùn birimù gbalẹ̀ ní Spain àti Portugal, lẹ́yìn tí iná mọ̀nà-mọ́ná déèdéè lọ

Alase nile ounjẹ kan re e to n fi ina foonu dana

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Alase nile ounjẹ kan re e to n fi ina foonu ṣiṣẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Inu okunkun birimu ni awọn agbegbe kan ni orilẹede Spain ati Portugal, wa bayii lẹyin ti ina deede lọ.

Iṣẹlẹ naa to kan awọn pupọ ninu awọn agbegbe to w ani orilẹede mejeeji, mu ki awọn baalu o ma le fo, irinajo ọkọ oju irin naa dawọ duro, bẹẹ ni lilọ-bibọ ọkọ paapaa, ko ja geere nitori pe ina ojupopo ko ṣiṣẹ.

Yatọ si awọn ibi wọn yii, awọn ileewosan ko ri iṣẹ ṣe, bẹẹni awọn inu ile, ati ile itaja naa ko ri ina lo.

Titi di akoko yii, awọn alasẹ orilẹede mejeeji ko ti i le sọ pato nnkan to fa bi ina ṣe lọ. Awọn iroyin kan n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ikọlu ori ayelujara, cyber-attack, ni.

Ni nnkan bi aago mejila ọsan ku iṣẹju mẹwaa, ni ina lọ.

Awọn eero to fẹ wọ ọkọ ojurin niluu Valencia, ko ri ọkọ ti yoo gbe wọn nitori aisi ina

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn eero to fẹ wọ ọkọ ojurin niluu Valencia, ko ri ọkọ ti yoo gbe wọn nitori aisi ina

Pedro Sánchez, olootu orilẹede Spain, ti sọ pe ki awọn araalu rọra maa lo foonu wọn lasiko yii, nitori adanwo to ti ba awọn irinṣẹ ibanisọrọ lorilẹede naa.

O ni ki wọn o lo foonu wọn fun ipe to ṣe koko, ti ko si ni i pẹrara titi atunṣe yoo fi waye.

Idiwọ ba lilọ-bibọ ọkọ lojupopo, nitori pe awọn ina to n ṣakoso oju ọna ko ṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idiwọ ba lilọ-bibọ ọkọ lojupopo, nitori pe awọn ina to n ṣakoso oju ọna ko ṣiṣẹ
Awọn to to fun ọkọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ina to lọ mu ki awọn eero to wa woran idije Madrid Open, lorilẹede Spain, tuka

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ina to lọ mu ki awọn eero to wa woran idije Madrid Open, lorilẹede Spain, tuka