Ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ l'Abuja

Igbẹjọ olori ẹgbẹ ajijagbara Ipob ilẹ Igbo, Nnamdi Kanu n lọ lọwọ nileẹjọ to ga julọ ni Naijiria niluu Abuja.
Mike Ozekhome, SAN to jẹ agbẹjọro Kanu n bẹ ileẹjọ lati fun un ni beeli.
Ẹbẹ keji ti agbẹjọro agba Ozekhome n bẹ ileẹjọ ni wi pe ki ileẹjọ pe ki wọn gbe Kanu kuro ni ahamọ ileeṣẹ DSS ki wọn si gbe e lọ si ọgba ẹwọn to wa ni Kuje l'Abuja.
Ẹwẹ, ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ dajọ tẹlẹ pe ki Kanu maa lọ lalaafia ti wọn si fagile gbogbo ẹsun ti ijọba fi kan an.
Koda ile ẹjọ kotẹmilọrun tun sọ pe o lodin lati fi Kanu si ahamọ.
Amọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun yii kan naa ni ijọba apapọ ti lọ gba aṣẹ lati teṣiwaju fifi olori ẹgbẹ Ipob si ahamọ titi ti ile ẹjọ to ga julọ yoo fi bẹrẹ igbẹjọ rẹ.
O yẹ ki ile ẹjọ to ga julọ ṣe igbẹjọ ni ọjọ kẹrinla oṣu Keṣan an to lọ, ṣugbọn igbẹjọ naa ko waye.
Ni ọjọ kọkanla oṣu Karun un ti igbẹjọ Kanu waye kẹyin ni ileẹjọ sun igbẹjọ siwaju lẹyin ti agbẹjọro ijọba Tijjani A. Gazali tako igbẹjọ ẹbẹ meji ti agbẹjọro Kanu n bẹ ileẹjọ.
Agbẹjọro Gazali bẹ ileẹjọ lati fun oun laye lati fesi si ohun ti agbẹjọro Kanu n beere lọwọ ileẹjọ.
Agbẹjọro Kanu, Ozekhome SAN, ni tiẹ sọ fun ileẹjọ pe oun ṣetan fun igbẹjọ nigba naa lọhun, amọ awọn adajọ sọ pe ko le ṣe igbẹjọ mọ lọjọ naa.
Ozekhome SAN tun bẹ ileẹjọ lati ṣe igbẹjọ naa laipẹ tori ipo ti ko dara ti Kanu wa ni ahamọ ileeṣẹ DSS.















