"Mo kórira ojú mi tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn rẹ báyìí"

Jono Lancaster, ẹni ọdun mẹtadinlogoji lo wa lati iwọ oorun Yorkshire ni orilẹede England.
Wọn bi arakunrin yii pẹlu alebu ara kan ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Treacher Collins’. To jẹ aarunh ninu ẹjẹ to ma se alebu si oju eeyan.
Eyi lo jẹ ki awọn obi Lancaster gbe ju silẹ nigba ti wọn bi saye.
Jono ba ileeṣẹ BBC sọrọ, o ni pe oun ka itan bi awọn obi oun se gbe oun ju silẹ nigba ti wọn bi saye.
“Mo joko ka akọsilẹ naa to ni awọn obi mi gbe mi silẹ nitori bi oju mi se ri o dẹru ba wọn pupọ.”
Awọn obi Jono gbe ju silẹ lẹyin wakati mẹrindinlogoji ti wọn bi, ti ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Jean si gbe lati se ma se itọju rẹ.
Ipo ti Jono wa jẹ ti awọn ọmọ ti eeyan ba bi ti ko ni egun ni bi to yẹ ko ti ni eegun lara.
Jean lo ofin lati asẹ lati ma se itọju Jono nigba to pe ọmọ ọdun marun un.
"Awọn ọmọ to ba ni ipenija ara ni Jean ma se itọju fun"
Jane ma se itọju awọn ọmọ to ba ni ipenija ara, eyi ti Jono jẹ ọkan lara wọn ọmọ naa.
Jono ranti asiko rẹ ni ile ẹkọ, to si jẹ asiko to dun mọ pẹlu gbogbo ijakulẹ to diju kọ.
O ni awọn ẹlẹgbọn agba kan wa ni ile ẹkọ ti wọn ma fi oju buruku wo, ti wọn yoo si kọrin eebu fun paapa to si dun wọ ninu eegun gan.
Nigba to dagba, to asiko lati ni ololufẹ, awọn ẹgbẹ rẹ bẹrẹ si ni ma ni ololufẹ sugbọn o nira fun lati ni ololufẹ nitori alebu to ni lara.
Nigba naa ni mo bẹrẹ si ni ma korira oju mi”
O ni oun bẹrẹ si ni ma korira awọn obi mejeeji to bi oun saye.
“Mo fẹ sọ bo se dun mi lọkan, inu ma bimi ti mo ba ti sọrọ nipa awọn obi mi.”
Awọn Obi Jono kọ lati ri lẹyin to dagba
Pẹlu gbogbo nnkan ti awọn obi rẹ se fun, Jono si fẹ wa awọn obi rẹ ri lati sọ fun w\pn pe alaafia ni oun wa, ti inu oun si dun.
O kọ lẹta si wọn sugbọn o gba e si pe wọn ko fẹ gbọ nnkan lati ẹnu rẹ.
“Lẹẹkansi, lati yago fun awọn eeyan meji yii, o dun mi gan.”
Lọwọlọwọ bayii, Jono n kọ iweto pe akọle rẹ ni ’Not All Heros wear Cap’, o ni eyi wa fun awọn eeyan ti wọn ti gbe aye se ohun rere pẹlu gbogbo ipenija ati ijakunlẹ ti wọn salabapada ninu irinajo wọn.
Iwe naa lo da le lori awọn eeyan ti Jono pada ninu irinajo rẹ, to si sapejuwe wọn gẹgẹ bi eeyan nla ati pe pun gan eeyan nla ni.
“Otitọ ibẹ ni pe, ifẹ lo kun gbogbo aye mi.”, eyi ọrọ ti Jono Lancaster, ẹni ti awọn obi rẹ ju silẹ sugbọn to ti di awukọse fun ọpọlọpọ sọ















