Customs vs Smugglers: Aṣọ́bodè dèrò ọ̀rùn lábúlé Fagbohun lẹ́yìn ìkọlù pẹ̀lú àwọn afurasí onífàyàwọ́ l'Ogun

Ajọ NCS

Oríṣun àwòrán, NCS

Oba oke ko ni jẹ ki a lọ si ajo alọ de o, agba adura ni.

Amọ ọrọ ko ri bẹ fun ẹṣọ aṣọbode kan to jẹ Ọlọrun nipe lẹyin ikọlu pẹlu awọn afurasi onifayawọ labule Fagbohun ni ijọba ibilẹ Yewa nipinlẹ Ogun.

Koda ohun ti a gbọ ni pe aṣọbode miran tun di awati lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun 2021 yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni abule Fagbohun nibi tawọn aṣọbode ti lọ ṣiṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ti a gbọ fidi rẹ mulẹ pe kete ti awọn afurasi onifayawọ yii foju gan ni ọkọ awọn ẹṣọ aṣọbode ni wọn da bajinantu bolẹ, ti ẹṣọ aṣọbode si di awati lẹsẹ kẹsẹ.

Ọjọru ni wọn ri oku ọkan lara awọn ẹṣọ meji to dawati ninu odo kan lẹba ilu Ajegun Iyaloosa eleyii ti ko si si ibọn rẹ lọwọ rẹ mọ.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Agbẹnusọ ẹṣọ aṣọbode, Theophilus Duniya to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe ọwọ ti ba awọn afurasi kan lori iṣẹlẹ naa.

Duniya sọ pe jẹjẹ lawọn ẹṣọ aṣọbode n ṣiṣẹ wọn kawọn onifayawọ yii to da rogbodiyan silẹ nibi ti ẹnikan ti dero ọrun ti ẹlomiran si di awati.

Agbẹnusọ ẹṣọ aṣọbode rọ awọn eeyan pe ki wọn ye doju ija kọ awọn ẹṣọ aṣọbode mọ.

''Iṣẹ ojọ wa ni a n ṣe, orilẹede Naijiria lo ran wa niṣẹ kii ṣe awa ni a ran ara wa.

Ofin ti ijọba apapọ gbe kalẹ ni awa n ṣe imuṣẹ rẹ, a ko ba ẹnikan ja.

Ẹ jọwọ ti ẹ ko ba ni iranwọ ti ẹ le ṣe fawọn eṣọ aṣobode, ẹ maa doju ija kọ wọn.

Awa naa ni ẹbi, bakan naa ni a ni ara ti yoo beere wa, lati ilu kan ni Naijiria ni awa naa ti sẹ wa.

Nitori naa, awọn naa lẹtọọ lati gbaye gbadun lorilẹede Naijiria lai si ẹnikan ti yoo ge ẹmi wa kuru,''agbẹnusọ ẹṣọ aṣọbode ṣalaye.

Ẹwẹ, iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan abule Fagbohun fi ilu naa silẹ lẹyin ti iṣẹlẹ yii waye tan nibẹ.

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ