Dino Melaye: Pápákọ̀ òfurufú ni Ọlọ́pàá ti mú mi

Sẹnetọ Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dino_melaye

Àkọlé àwòrán, O ti pẹ ti awọn ọlọpa ti kede pe awọn n wa melaye

Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ Sẹnetọ Dino Melaye.

Gẹgẹ bii iroyin naa ṣe sọ, awọn ọlọpaa mu Sẹnetọ Melaye ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe nilu Abuja.

Asiko to n lọ si orilẹede Morocco fun isẹ ilu ni wọn mu Melaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ti pẹ ti awọn ọlọpa ti kede pe awọn n wa melaye lori ẹsun didi ihamọra nnkan ija ogun fun awọn janduku kan.

Awọn janduku naa ni wọn darukọ Sẹnetọ Melaye nigba ti ọwọ awọn agbofinro tẹ wọn ni ipinlẹ Kogi.