Banji Akitoye: 'Yoruba Nation' nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Iran Yoruba lo ni iwa omoluwabi ati ọpọlọ pipe- Ojogbon Banji Akitoye.

Olori Ilana Omo Oodua to n ja fun ominira iran Yoruba kuro labẹ orilẹ-ede Naijiria gbalejo BBC Yoruba.

Ojogbon Banji Akitoye sọrọ pupọ lori idi mẹrin ti iran Yoruba se gbọdọ kuro labẹ isejoba Naijiria lapapọ.

Kini Olori Ilana Oodua tun sọ?

Ojọgbon Banji Akitoye ni pe abuja kan ko si lorun ọpẹ ju pe ki iran Yoruba da duro lọ.

Baba agba to n sakoso Ilana Omo Oodua menuba bi awọn ọmọ Yoruba se n lu aluyo nilẹ okeere nitori pe ọlọpọlọ pipe to ni iwa omoluwabi ni wọn jẹ.

Sunday Igboho ati Banji Akitoye

Oríṣun àwòrán, others

Wo ọ̀rọ̀ Ojọ́gbon akitoye lori ohun to kan fun Sunday Igboho?

Baba ni pe o to gẹ, iran Yoruba setan lati da duro laibẹru.

O ki awọn akọni iran Yoruba laya pe ki wọn ma ṣojo nitori pe àlá Oduduwa Nation yoo wa si imuṣẹ.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Akitoye pe ki awon eeyan Yoruba fi ọkan bale lori Oloye Sunday Igboho.

O ni pe laipẹ ni Sunday Igboho yoo pada wa sile ni Ibadan ni Naijiria.

O ni pe ki wọn maa reti Igboho Ooṣa laipe laijinna nitori pe ko sewu.