Josephine Iyamu ṣe fàyàwọ ọmọbinrin 5 lọ Germany

ilé Josephine Iyamu
Àkọlé àwòrán, Josephine Iyamu ló máa ń seto ìtrina fun àwọn obinrin tó ba fẹ kó wọ Germany fun iṣẹ asẹwo

Ilé ẹjọ́ ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì tí ju ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó jẹ́ nọ́ọ̀sì sẹ́wọn nítorí kíkó àwọn obinrin ló sí orílẹ̀-èdè Germany fún iṣẹ́ àṣéwó.

Àkọlé fídíò, Ilé ẹjọ́ Brimingham jẹjọ́ Josephine Iyamu tó ń se fayawọ

Ilé ẹjọ́ ọ̀hún tó fi London ṣe ibujókò fẹ́sùn kan Josephin Iyamu pé ó ṣe fàyàwọ́ obìnrin márùn-ún láti ìpínlẹ̀ Edo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹrí lẹ̀yìn ìwádìí BBC fi han pé Josephine máa ń fipa mú àwọn obinrin náà láti mulẹ̀ pẹ̀lú òun fún ìdánilojú pe wọn o máa kó owo wọn fún un

Iyamu to jẹ́ ẹni ọmọ ọdún mọ́kànléláàdọ́ọ́ta jẹ̀bi ẹsùn oní pele márùnùn pé ó ń ṣètò ìrìnàjò àwọn obinrin fun iṣé aṣẹ́wó, àti pé ó ń dẹ̀nà ìdájọ́ nílé ẹjọ́ Brimingham

Lásìkò ètùtù tí ó máa ń ṣe, yóò fi típa mú àwọn obìrin náà láti jẹ ọkàn ẹdìyẹ, mu ẹ̀jẹ̀ tí ó ní ìdin nínú tí wọ a sì ku àtíkè sójú àpá ti bá dá sí wọn lára

Iyamu ní ẹni àkọ́kọ́ tí wọn fi jofin lábẹ́ òfin tuntun ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì fún ìmúni sìnrú tó fi mọ ẹni to ṣẹ lẹ́yìn odi ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì.