Cameroon wa ìyà mu bíi gaàrí lọ́wọ́ England, 3-0 ló bá dé

aworan agbabọọlu Cameroon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Niṣe ni ẹkun gba ẹnu awọn agbabọọlu Cameroon lẹyin ti VAR fagile goolu ti wọn jẹ

Wọn ṣe iwọn ti wọn le ṣe amọ, ikọ agbabọọlu obinrin orileede Cameroon ti fidirẹmi lọwọ England pẹlu ayo mẹta si odo.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣere Stade du Hainaut ni Valenciene Cameroon ja fitafita ṣugbọn o jọ bi pe VAR pawọpọ pẹlu ikọ England lati ja ireti wọn kulẹ.

Steph Houton lo kọkọ jẹ goolu akọkọ ni iṣẹju kẹrinla ti Ellen White si fi ikeji si awọn Cameroon ni iṣẹju kaarundinlaadọta le diẹ.

Cameroon nikan ni ikọ orileede Afrika to ṣẹku ninu idije naa amọ bayi,wọn ti darapọ mọ orileede Naijiria lati ko ẹru wọn pada wa sile.

Pẹlu abajade ifẹsẹwọnṣẹ yi, England yoo tẹsiwaju si abala tokangun si kelyi to kangun si aṣekagba idije naa.

aworan agbabọọlu Cameroon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Niṣe ni ẹkun gba ẹnu awọn afgbabọọlu Cameroonlẹyin ti VAR fagile goolu ti wọn jẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: