Victor Moses: Ọmọ pásítọ̀, ìjà ẹ̀sìn ni Kaduna fa ikú àwọn obí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Victor Moses kede pe oun ti fẹ̀yinti lẹyin to ti gba idije mẹtadinlogoji fun Naijiria ní Ọjọru.
Ọpọ ọrọ ni àwọn eniyan ti sọ loju òpó facebook BBC Yoruba lori eyi. Diẹ nibẹ ni:

Bee naa ni àwọn mii gba pe igbesẹ to dara fun un lo gbe pe:

Ẹ wo ọrọ awọn mii ni ori bbc news Yoruba ni facebook yin ati @bbcnewsYoruba lori instagram wa.
Àwón nkan ti o ṣeeṣe koo ma mọ nipa Victor Moses
Njẹ ẹ mọ pe ibanujẹ ni Victor Moses fi di ọmọ Ilẹ Gẹẹsi? E gbe awọn nkan mẹ́sàn-án nipa atamatase Super Eagles ti ẹ le ma mọ wọnyi yẹ wọ:
- Ọdun mọkanla ni Moses wa ni ọdun 2001 nigba ti awọn obi rẹ ku ninu ija ẹlẹsin-mẹsin kan ni Ipinlẹ Kaduna.
- Ọsẹ keji ti wọn pa awọn obi rẹ ni awọn ẹbi rẹ gbee lọ si Ilẹ Gẹẹsi lati lọ ṣe atipo.
- Oribamiṣe ni ọrọ Moses, nitori pe, ibi to ti n gba bọọlu ni ile iwe rẹ, ni ẹka awọn ọdọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Crystal Palace ti wa mu.
- Oṣu kẹsan an ọdun 2012 ni Moses gba ifẹsẹwọnsẹ akọkọ nigba to de Chelsea
- Ẹgbẹ agbabọọlu mẹta - Liverpool, Stoke City ati West Ham United - lo ti ya Moses lo lọwọ Chelsea laarin ọdun 2013 si 2016.
- Ilẹ Gẹẹsi ni orilẹ-ede ti agbabọọlu naa kọkọ gba bọọlu fun.
- Ife ẹyẹ Afrika ti 2013 ni idije ti Moses kọkọ gba fun ikọ Super Eagles.
- Moses ni ọmọ meji - ọkunrin kan ati obinrin kan.
- Ami ayo mejidinlọgọta lo ti gba wọle fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ti ba ṣiṣẹ ati Super Eagles.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu atẹjade to Moses fi kede ifẹyinti rẹ, o ni, "Mo ti fẹnu ba awọn igba to dara ju laye mi nigba ti mo wọ aṣọ iko Super Eagles, mi o le gbagbe awọn akoko naa fun igba pipẹ.
Ṣugbọn mo lero wi pe asiko ti to lati yẹba, ki n ba a le fọkan si ẹgbẹ agbabọọlu ti okeere ti mo n ṣiṣẹ fun ati idile mi. Mo fẹ ki awọn ewe to n bọ lẹyin le ri aaye wọle."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Moses wa lara ikọ to ba Naijiria gba ife ẹyẹ ti Afrika ni 2013, to dẹ tun kopa ni ife ẹyẹ Afrika to waye ni 2014 ati 2018.














