World Cup 2018: Argentina fàgbà han Nàìjírìa pẹ̀lú àmì ayò 2-1

Argentina àti Nàìjírìa
Àkọlé àwòrán, Argentina tún y'ọwọ́ Nàìjírìa nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé ní Russia

Argentina ti y'ọwọ Nàìjírìa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti o n lọ lọwọ lẹyin ti Argentina fun wọn ni ami ayo meji si ẹyọkan 2-1

Lionel Messi lo kọkọ gbayo wọle fun Argentina ki Victor Moses to dapada fun Nàìjírìa pẹlu ''penalty.''

Marcos Rojo lo gba ayo keji wọle ti Argentina fi jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àkọlé fídíò, Argentina tàbi Nàìjíríà?

Croatia fagba han Iceland pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan ninu ifẹsẹwọnsẹ miran to waye ni isọri kẹrin.

Croatia lo ṣe ipo kinni ninu isọri naa ti Argentina si ṣe ipo keji.