Ijọba Nàìjíríà pinnu láti dá àwọn èèyàn lókowò N10,000

ẹni to n ta èso

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́

Ọṣinbajo ni káàdì ìdìbò kọ́ ni wan a fi san ẹgbẹrun mẹwaa náà fáwọn ènìyàn.

Ijọba Naijiria ti kede pe wọn yoo pese ẹgbẹrun mẹwaa owo iranwọ fawọn oniṣowo keekeeke jakejado Naijiria.

Lẹyin tijọba ṣe ìkede yii ni BBC jade lọ ṣe iwadii oriṣii irufẹ ọja tabi okòwò ti èèyàn le fi ẹgbẹrun mẹwaa naira ṣe lasiko yii pẹlu bi ìta ṣe rí.

Ọpọlọpọ lara awọn ti BBC ba sọrọ ni àwọn ti sẹ okowo loriṣii pẹlu owo ti kò to ẹgbẹrun mewaa naira sẹyin.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

Díẹ̀ lára àwọn okòwò tí ó ṣeéṣe lásìkò yi pẹlu N10,000

Iwadii BBC fihan pe eniyan le maa ta aṣọ àlòkù oyinbo ti àwọn kan n pe ni òkìrìkà ni ẹyọ.

Awọn mii gba pe ẹni ti kò ba ni itiju iṣẹ le maa ta èso bii ọsan, ibẹpẹ, ọ̀pẹ̀ oyinbo àti bẹẹ bẹẹ lọ.

obinrin kan to n kiri nkan mimu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ibi gbogbo lo gba alagbara

Àwọn oniṣowo kan sọro lori tita ohun mimu tutu bii ẹlẹrindodo ati omi tutu ninu ọ̀rá àti nínú ike.

Ero awọn miran ni síse ounjẹ ta nitori wi pe, ojumọ kan kò ni mọ́ ki ẹnu má gba ẹbọ ounjẹ.

olounje

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, olounjẹ ni oloogun ebi

Imọran àwọn oniṣowo mii ni pe ki wọn maa ta àwọtẹlẹ obinrin bii kọ́mú àti pátá àti tọkunrin naa ni èrè lórí ti ko si nilo owó okowo to pọ ju.

awọtẹlẹ obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọ̀lẹ nìkan lààyè kó gbà.

Igbagbọ awọn mii nipe àtẹlẹwọ́ ẹni kìí tan ni jẹ. Pe iṣẹ́ ọwọ́ ni o yẹ ki èèyàn fi ẹgbẹrun mẹwaa naa dá silẹ̀ ki o le maa mu owó wole sii.

onidiri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àtẹlẹwọ ẹni kò le tan ni jẹ

Oriṣi iṣẹ ọwọ bii aránṣọ, irun gigẹ, irun dídì, kafinta àti bẹẹ bẹẹ lọ.

Omiran tun ni iṣẹ alagbafọ aṣọ fifọ ni eyi to dabi apọnmita ti ko le kuna loju awọn kan.

aso fifo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Alagbafọ ko le ṣai ṣere eti odo
Àkọlé fídíò, Bimpe: Èèyàn bíi tiyín ni àfín, ẹ dẹ́kun dídẹ́yẹsí àfín
Àkọlé fídíò, SMS alert: Wo ọ̀nà láti dẹ́kun jìbìtì lórí àṣùwọ̀n báǹkì rẹ