World Cup 2018: Salah yóò kópa nínu ìdíje Russia vs Egypt lọjọ Iṣẹgun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìrètí wà pé Salah yóò gbógo fun Egypt nínú ìdíje Russia 2018.
Awọn ikọ agbabọọlu ilẹ Adulawọ ko tii rọwọ mu daadaa ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ ni Russia yii.
Egypt, Morocco, Nigeria ati Tunisia ti padanu ninu awọn idije akọkọ wọn.
Tunisia ni orilẹ-ede ilẹ Afrika to kọkọ gba ami kan wọle ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti Russia 2018.
O ku Senegal bayii ti gbogbo ojú wà lara wọn boya wọn a yọ ikọ Afrika kuro ninu ẹgan yii.
Akọnimọọgba Egypt, Hector Cuper, ti ni Mohamed Salah yoo kopa ninu idije to m bọ lọla laarin Russia to n gbalejo idije World Cup 2018 ati Egypt ti o ba ti yege ninu ayẹwo to fẹ ṣe.
O ni: "Ara Salah ti ya, a ni ireti pe yoo gba bọọlu pẹlu ara lile. A kọkọ rò pe ara rẹ ti ya tẹlẹ ni ṣugbọn yoo ṣe ayẹwo aṣepari ṣaaju idije naa pẹlu Russia".














