Nàìjíríà kò na England ri nínú ìdíje bọọlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ Super Eagles ati ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi n tẹsiwaju ninu igbaradi wọn fun ife ẹyẹ agbaye Russia 2018
Awọn ikọ agbabọọlu mejeeji yoo koju ara wọn ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ ní pápá ìṣeré Wembley lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Bayi ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ marun un to kẹyin ti awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji kopa ninu rẹ ti lọ:
1. Ikọ Super Eagles ilẹ Naijiria ta ọ̀mì alayo kọọkan pẹlu orilẹ-ede DR Congo lọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2018 nilu Port Harcourt.
2. Ẹgbẹ agbabọọlu Nigeria fidi rẹmi pẹlu ayo meji sodo nigba ti wọn koju orilẹ-ede Serbia ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ nilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Ikọ Super Eagles fagba han Poland pẹlu ami ayo kan lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2018.
4.Ẹgbẹ agbabọọlu Nigeria fakọyọ bi wọn ṣe fagba han Argentina pẹlu ayo mẹrin si meji ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ l'orilẹ-ede Russia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Ikọ Super Eagles ta omi alayo kọọkan pẹlu orilẹ-ede Algeria ninu ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ti wọn fi pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.
Three Lions ti England
1. Fun orilẹ-ede Gẹẹsi, ọ̀mi ni ikọ Three Lions ta pẹlu orilẹ-ede Italy ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2018.
2. Ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi fagba han orilẹ-ede Holland pẹlu ami ayo kan sodo lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Ọmi ni ẹgbẹ agbabọọlu Three Lions ta ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ miran pẹlu orilẹ-ede Brazil lọjọ kẹrinla, osu kọkanla ni ọdun 2017.
4. Ẹgbẹ agbabọọlu Ilẹ Gẹẹsi tun ta ọ̀mi pẹlu orilẹ-ede Germany ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ lọjọ kẹwa, osu kọkanla ni ọdun 2017.
5. Ikọ Three Lions jawe olubori pẹlu ami ayo kan nigba ti wọn koju Lithuania ninu ifẹsẹwọnsẹ to kẹyin ti wọn fi pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nàìjíríà ati England ti pade lẹmeji ri ti England si gbegba oroke pẹlu ami ayo kan ninu ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ to waye ni ọdun 1994 nilẹ Gẹẹsi.
Omi ni wọn ta nigba ti wọn pade ara wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye Korea Japan 2002.












