EndSARS: Oṣù mẹ́fa lẹ́yìn ìwádìí ìgbìmọ̀, ìjọba Naijiria kò ṣe ohunkóhun

Lẹyin oṣu mẹfa ti igbimọ ti ijọba gbe kalẹ lẹyin iwọde EndSARS pari iṣẹ tan, ajọ ajafẹtọ kan ti fẹsun kan ijọba pe ko gbe igbesẹ kankan lori abọ iwadii igbimọ naa.

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Human Rights Watch ti ke si ijọba Naijiria lati ṣiṣẹ lori abajade abọ iwadii naa, ko si foju awọn ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori wina ofin.

Human Rights Watch ni "Ko yẹ ki ijọba sun abọ iwadii igbimọ naa sẹgbẹ kan lai jẹ ki idajọ ododo waye lori awọn to ku nibi iwọde naa lọdun 2020, atawọn to ṣina ibọn fun awọn oluwọde.

Ajọ naa sọ ninu atẹjade kan pe ikuna lati ṣedajọ ododo lori abajade igbimọ #EndSARS le mu ki awọn araalu maa ro pe ijọba ko kọbi ara si ẹtọ awọn, o tun le fun awọn agbofinro ni igboya lati maa tẹ ẹtọ awọn araalu mọlẹ.

Ogunlọgọ awọn ọdọ lo tu jade ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 lati ṣe ifẹhomuhan tako iwa ipa ti awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, SARS, maa n wu si awọn araalu, ti wọn si ni awọn n fẹ ki ijọna wọgli le ẹka SARS naa pẹlu ami #EndSARS.

Awọn olufẹhonuhan fẹsun kan awọn agbofinro pe wọn fiya jẹ awọn, wọn tun ṣina ibọn fun awọn pẹlu.

Eyii to buru ju lo waye ni iloro Lekki Toll Gate niluu Eko, lẹyin ti iroyin ni awọn ọmọ ogun ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde ni iloro naa.

Igbimọ ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lẹyin iṣẹlẹ naa sọ pe lootọ ni awọn ologun dana ibọn ya awọn oluwọde ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ọhun.

Igbimọ naa gba ijọba nimọran lati fi iya to tọ labẹ ofin jẹ awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori, ati pe ijọba gbọdọ san owo gba mabinu fun awọn araalu ti ọrọ naa kan.

Lẹyin abajade iwadii naa ni ijọba ipinlẹ Eko ni oun gba abajade naa wọle, ayafi koko kan ninu rẹ.

Kini o kọkọ ṣẹlẹ nipa ẹtọ awọn obinrin ni ibomii?

Ẹ kò gbọdò lo 'Make Up'; ya 'tatoo'; fi kún èékánná tàbí kun àtíkè níta mọ́ lábẹ́ òfin wa- Iran

Orilé-ede Iran ti gbe ofin tuntun kan kalẹ fawọn obinrin lati maa tẹle.

Ìlú kàn rèé tí ṣiṣe ará loge lè mú ẹ kò sí pampẹ́ òfin

Wọn ti fofin de awọn orisi imura kan fawọn obirin ni ilu Mashshad to jẹ ilu to tobi sikeji ni orileede Iran.

Gẹgẹ bi olori ẹgbẹ awọn aserenloge ni ilu naa se wi, awọn nkan ẹsọ ara obinrin ti wọn fofin de la ti ri ni: 'make up' obinrirn, irinsẹ ti wọn fi n tun eekanna se, eleyi ti wọn fi n kun eekanna, yiya aworan si ara ti a mọ si 'tatoo' ati kikun atike oju.

O ni wọn gbe igbesẹ yi ni ibamu pẹlu ofin ẹsin nibẹ ti eleyi si ti mu ki ọpọ awọn ile asaraloge ti kogba nile.

Olori ilu naa si ti kede pe awọn ọlọpaa sharia yoo maa kaakiri ilu lati ri pe wọn tẹle asẹ yi.

Mashhad jẹ ilu tawọn to n rinrinajo ẹsin maa n wa gan an ni orilẹ-ede Iran.

Lọdọọdun ni awọn arinrinajo ẹsin to le ni miliọnu maa n wa lati se abẹwo si oju oori Imam Reza

Wọn fofin de ki awọn obinrin maa lo awọn nkan asaraloge kan ni Iran to fi mọ sise ''massage''