Alaafin burial: Mọ̀ síi nípa ìgbésẹ̀ tó ń wáyé ní aàfin lẹ́yìn ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lati ọjọ Abameta, Ojọ kẹtalelogun, oṣu kẹrin, ọdun 2022 nti Oba Lamidi Adeyemi ti waja ni aaya ti bẹ silẹ to bẹ si are ni ilu Oyo.Wo ohun tó yẹ kó mọ nípa Baràá ibùgbé ìkẹyìn Aláàfin Olayiwola Adeyemi

Lati igba naa si ni eto orisiirisii ti bẹrẹ titi ara Iku Baba Yeye fi wọ kaa ilẹ lọ ni Baraa lẹyin ti wọn kirun si Oba Atanda Olayiwola lara tan ni aafin OyoIrú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo.

Oro Ije bẹrẹ loni ni Oyo:

Oni ọjọ́ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2022 ni o pe ọjọ keje ti Oba Lamidi Adeyemi re iwalẹ aṣa.

Awọn Oniṣẹsẹ ṣeto Orò Ije fun Alowolodu to lọ darapọ mọ awọn baba nla rẹ.

Láti oju ite ni awon egbe awo ati awon omo ode ti rin pada sii ààfin Kabiyese

Wo awọn iṣẹlẹ Manigbagbe to waye nibẹ ninu fọnran fidio yii:

Kini awọn ọjọgbọn ninu itan sọ?

Ọ́jọgbọn Ogundiran sọ pe ''Pipadanu iru aaye aṣa bayi a ko le sọ iru ipa ti yoo ni nitori bo ba fi le parun, adanu nla leleyi yoo jẹ ti ko si ṣe maa ba ni feti gbọ rara ati rara''

Ẹwẹ,a gbọ pe Ogundiran ti ṣaaju kan si Alaafin Lamidi Adeyemi ko da si ọrọ atunṣe oori awọn Oriade yi nigba to ṣi wa laye.

A ko ribi fidi ọrọ naa mulẹ ṣugbọn ko jọ pe Alaafin to jẹ olugbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe Yoruba ṣe nkankan lori atunṣe Bara.

Boya bayi ti Alaafin naa ti wọ kaa ilẹ sun nibẹ,awọn to n bọ́ lẹyin le wa ṣe atunṣe ati igbelarugẹ aaye yi ko ba le jọju bo ti ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Mọ̀ síi nipa igbesẹ to n waye lẹ́yin ti Alaafin ti re iwalẹ aṣa ni Oyo.

Bi awọn kan ṣe n b eere nipa Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Alaafin Oba Lamidi Adeyemi rè éWo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Naa ni awọn mii n beere sii nipa Ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn Olori Alaafin rè é léyìn tó wàjàWo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn

Ọba Lamidi Adeyemi lo papoda lẹni ọdun mẹtalelọgọrin ni Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni awọn mii tun n beere nipa bi eto isinku rẹ sẹ lọ.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀

Gbogbo ohun ti ẹ fẹ mọ nipa Oba Alowolodu, Iku Baba Yeye Atanda Olayiwola Adeyemi keta ni BBC Yoruba n mu wa fun un yin nitori pe a mọ pataki aṣa ati iṣe iran Oodua.Wo Alàáfin 43 tó jẹ́ láti ìgbà ìwásẹ̀ ṣáajú Lamidi Adeyemi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wàjà

Eto isinku Alaafin gan an ko i tii waye

'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'

Onimọ nipa iṣẹṣe naa ni ilẹ Yoruba kii ṣe ilẹ Arabu, tabi ẹlẹsin Juu to fi mọ Kristẹni nitori naa o di dandan ki wọn sin Alaafin ni ọna ti ilẹ Yoruba bi o tilẹ jẹ pe wọn ti sin ni ọna Islam.

Ọjọ Kẹsan ati Ikẹtadinlogun ni awọn ọjọ pataki ti wọn yoo ṣe awọn ohun ti wọn fẹ ṣe ni ọna iṣẹṣe.

Ọba kọọkan lo ni ibi ti wọn yoo sin si ti wọn n pe ni Baare, idile kọọkan lo si ni iboji ti wọn maa n sin won si wa.Wo ohun tó yẹ kó mọ nípa Baràá ibùgbé ìkẹyìn Aláàfin Olayiwola Adeyemi

Tani yóò máa tukọ̀ aafìn Oyo lasiko yii?

Bashọrun ni yoo saaju titun afin to leyin ipapoda Alaafin.

Oloye Ifayemi Elebuibon ni ṣiṣe afọmọ afin ti Alaafin ilu Oyo ni yoo pari gbogbo eto isinku ọba

Eleyii ni yoo ṣi ọna silẹ fun ọba tuntun miran lati jẹ.

O ni Bashorun yoo ṣe ipade pẹlu ile ọba to kan, ti wọn yoo si bere lọwọ ifa bi wọn yoo ṣe yan ọba miran.

Lẹyin ti wọn ba yan ọba naa tan, ni iṣẹṣe yoo ṣẹṣẹ bẹrẹ fun ọba tuntun naa.

Wọ́n máa'tó ṣe ayẹyẹ Ìje Alaafin Oba Lamidi Adeyemi

Ọba tuntun le e fẹ awọn iyawo Alaafin to ba wu u.

Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta fi awọn iyawo to rẹwa lorisirisi silẹ ni aafin ko to wọ kaa ilẹ sun, awọn ti wọn n pe ni olori.

Awọn olori Alaafin pọ ti ko si ẹni to si le e sọ iye pato ti wọn jẹ ni gbangban.

Lara awọn iyawo ọba to waja naa ni Olori Abibat, Olori Memunat, Olori Damilola Olori Anuoluwapo, Olori Mojisola, Olori Ola Badirat, Olori Folashade, Olori Omobolanle, Olori Rukayat Abbey Adeyemi, Olori Rahmat Adedayo, Olori Mujidat, Olori Ajoke, Olori Omowunmi ati Olori Moji Queen Damilola.

Amọ alukoro fun ile ọba ni awọn iyawo Alaafin n ṣe idaro iku ọba lọwọ, ti wọn yoo si ṣe gbogbo eto to yẹ lati ṣe eto to ye fun ọba to waja.

Lẹyin eyi ni awọn iyawo ọba le kuro ni afin lati tẹsiwaju ni ọna wọn.

Kíni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn Olori Alaafin tí wọ́n kò fẹ́ dúró ní Aafin mọ́ lẹ́yìn àfọ̀mọ́?

Amọ awọn to ba gba lati duro si afin ni ẹtọ lati duro si ibẹ, ti ọba tuntun yoo si ma a tọju wọn.

Ko si ohun to n jẹ abobaku mọ.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo jẹyọ lẹyin iku Alaafin paapaa lori ẹrọ ayelujara.

Lara ohun ti awọn eniyan sọrọ nipa rẹ ni ọrọ abobaku, ti awọn Yoruba ma n ṣe ni igba aye atijọ ti eniyan kan yoo tẹle ọba de saare, ni igbagbọ pe yoo ma a ṣe ẹru ọba ni ọrun alakeji.

Amọ Baba Elebuibon ni ko si ohun to jọ mọ ati pe ọdun 1935 ni awọn oyinbo ti fofin de asa naa nitori ko mu ọpọlọ dani.

Amọ o ni isinku ọba yoo mu ẹjẹ dani, amọ kii ṣe ti ọmọ eniyan.