Timothy Adegoke: Ìgbẹ́jọ́ Ikú Timothy Adegoke ń tẹ̀síwájú lónìí, Agbẹjọ́rò Femi Falana balẹ̀ sílé ẹjọ́

Ile ẹjọ ti sun igbẹjọ siwaju, lori ẹjọ ẹsun iku akẹkọọ Fasiti OAU, Timothy Adegoke.

Nibi ijoko ile ẹjọ to waye ni ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni Onidajọ Oyinkansola Adepele, ti kede ọjọ tuntun.

Eyi waye lẹyin ti agbẹjọro agba, Femi Falana, ri aṣẹ gba lọwọ ijọba ipinlẹ Osun, lati jẹ agbẹjọro fun idile Adegoke, to jẹ olupẹjọ.

Nibi igbẹjọ to foriṣanpọn lonii, awọn agbẹjọro awọn afurasi sọ fun ile ẹjọ pe ẹnikan lara awọn afurasi mẹfa, n ṣe aisan.

Iwe iroyin Punch jabọ pe afurasi naa, Magdalene Chiefuna, deede bẹrẹ si ni hu ikọ, to si ṣubu lulẹ laipẹ ti igbẹjọ bẹrẹ.

Agbẹjọro Rasheed Murtala tẹsiwaju pe awọn nilo asiko si lati gbaradi fun awọn ẹlẹrii ti awọn nilo nile ẹjọ.

Ṣaaju ni agbẹjọro Femi Falana tako ibeere wọn, ṣugbọn nigbẹyin, Onidajọ Adepele pada gba ẹbẹ wọn, to si sun igbẹjọ si oṣu to n bọ.Ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ti sun igbẹjọ siwaju, lori iku to pa akẹkọọ Fasiti OAU, Timothy Adegoke.

Ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ń tẹ̀síwájú lónìí, Agbẹjọ́rò Femi Falana balẹ̀ sílé ẹjọ́

Lónìí ni ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ onípele kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo, Ile Ife yóò tún máa tẹ̀síwájú.

Bí a bá ṣe ń kó ìròyìn yìí jọ, gbajúgbajà agbẹjọ́rò àti ajafẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Femi Falana ti wà ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó wà ní ìlú Osogbo.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní Femi Falana kéde wí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti fún òun ní àṣẹ láti gba àkóso ẹjọ́ náà.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni wí pé Femi Falana ni agbẹjọ́rò tí yóò máa dúró fún mọ̀lẹ́bí Timothy Adegoke níbi ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ́wọ́ náà.

Ní báyìí àwọn afurasí èyí tí Ramon Adedoyin tó jẹ́ ẹni tó ni ilé ìtura Hilton, Ile Ife níbi tí akẹ́kọ̀ọ́ náà kú sí àti àwọn mẹ́fà mìíràn ti balẹ̀ sí ilé ẹjọ́.

ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ẹ ó rántí pé àjọ ọlọ́pàá ti wọ́ ẹni tó ni ilé ìtura Hilton náà, Dókítà Ramon Adedoyin àti àwọn mẹ́fà mìíràn lọ sí ilé ẹjọ́ gíga kan nílùú Abuja lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sí ilé ìtura náà lọ́jọ́ kẹfà, oṣù kọkànlá, ọdún 2021.

Lẹ́yìn èyí ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun lẹ́yìn tí wọ́n pé fùn gbígbé ẹjọ́ náà lọ sí ìpínlẹ̀ náà nítorí níbẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ná[ti wáyé.

Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn Adedoyin ni sínsin òkú Adegoke lọ́nà àìtọ́, pípa ẹ̀rí ìwé owó tí Timothy Adegoke fi san owó rẹ́ àti yíyọ ẹ̀rọ ayàwòrán (CCTV) ilé ìtura náà rẹ́ lójúnà àti pa àwọn ohun tí kò bá jẹ́ ohun ẹ̀rí rẹ́.

Ẹ̀sùn ìpànìyàn, ìlẹ̀dí-àpòpọ̀, àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn ni wọ́n fi kan àwọn mẹ́fà tó kù.