You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aisha Buhari Iftar: Ẹ fi àwọn obìnrin ṣe ìgbákejì olùdíje yín gbogbo, Aisha Buhari pàrọwà fáwọn ẹgbẹ́ òṣèlú
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria Aisha Buhari ti ke sawọn ẹgbẹ oṣelu lati maa fi ti awọn obinrin ṣe lati du ipo igbakeji aarẹ fun gbogbo awọn oludije wọn.
Lasiko to fi n sọrọ nibi apejẹ iṣinu awẹ Ramadan, Iftah to pe nile ijọba to wa nilu Abuja fawọn oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu gbogbo lorilẹede Naijiria.
Aya aarẹ pe apejẹ Iftar naa lọna ati lee fun awọn oludije gbogbo lanfani ati fi ifẹ ati ajọyọ han si ara wọn ni ibamu pẹlu ilana Ramadan ati idagbasoke orilẹede Naijiria.
Aisha Buhari ni ohun to lee duro deede fawọn obinrin ninu oṣelu ni lati rii pe wn lanfani si awọn ipo oṣelu gbogbo to ba wa nilẹ.
"Asiko to ki a lo awọn obinrin fun ipo igbakeji awọn oludije ni gbogbo ẹka ipo oṣelu gbogbo nitori bi wọn ṣe maa n pọ to ni ti ọrọ idibo."
Aya aarẹ orilẹede Naijiria wa rọ gbogbo awọn oludije lati ni afojusun lori awọn ohun ti yoo tubọ mu ki orilẹede Naijiria gberu sii ninu iṣọkan, ibaraẹniṣepọ bi ọmọ iya ati igbọraẹniye.
Bakan naa lo rọ wọn lati ni akoyawọ ki wọn si yago fun awọn ohun to lee fa wahala, idarudapọ ati jagidijagan nipa ninawọ ifẹ lasiko to ba yẹ, paapaajulọ lasiko ipolongo ibo.
Bakan naa lo tun rọ wọn lati kọ ẹkọ pẹlu abajade eto idibo ọdun 2015 ninu eyi ti ko si ọrọ a n pẹjọ tabi wahala kankan lẹyin rẹ nile ẹjọ.
O ni eyi gan an ni ẹbun opin saa ti awọn ọmọ Naijiria lee fi ki ẹbi aarẹ pe o digba kan naa.
Lara awọn oludije ipo aarẹ to wa nibi apejẹ iṣinu awẹ Ramadan naa ni aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, Minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Sẹnetọ Chris Ngige, Gomina Dave Umahi tipinlẹ Ebonyi ati akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed.