South Korea: Èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ajá mọ́

Ile ẹjọ kan ti pase ki wọn ma pa aja fun ẹran jijẹ mọ̀ ni ilu South Korea.

Idajọ̀ naa jẹ ohun to jẹ idunnu fun awọn ajafẹtọ ẹranko.

Wọn ni wi pe eyi yoo sọ ẹran aja jijẹ di ohun itan ni ilu naa.

Ẹran aja je ounjẹ pataki ni South Korea lati ọjọ pipẹ, ti wọn si maa n jẹ to aja milionu kan lọdọọdun.

Saaju asiko idajọ yi, jijẹ ẹran aja ko wọpọ mo ni ilu naa nitori awọn ara ilu naa ti n sọ aja di nkan osin.