Jonathan the tortoise: Wo ìjàpá ọdún 190 tó jẹ́ ẹranko oríilẹ̀ tó dàgbà jù láyé

Bo tilẹ jẹ pe a ko mọ ọjọ ibi ijapa aranbara Jonathan, awọn onimọ sayẹnsi gbagbọ pe Jonathan yoo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi aadọwa rẹ lọdun 2022 yii.

Eyi lo jẹ ki ijapa yii jẹ eranko oriilẹ to dagba julọ laye.

Saint Helena ni Jonathan n gbe ni Erekusu okun South Atlantic.

Igbagbọ ni pe lati orilẹ ede Seychelles ni ijapa ti wa l'ọdun 1882.

Lori ilẹ oko kan ni Erekusu okun naa ni Jonathan n gbe nile gomina St. Helena.

Jonathan gbajumọ ni Erekusu okun to n gbe debi pe aworan rẹ lara owo ẹyọ "5p" St Helena.

Oun nikan kọ ni o n dagbe, Jonathan n gbe pẹlu awọn ijapa nla mii bii David, Emma ati Fred.

Fọto ti wọn ya lọdun 1882 fihan pe Jonathan ti dagba ki wọn to gbe e wa , koda, awọn onimọ sayẹnsi sọ pe o ti pe aadọta ọdun nigba naa.

Amọ, o ṣẹṣẹ wọ inu iwe itan ni gẹgẹ bi ẹranko onipẹpẹ to dagba julọ laye.

Iru Ounje wo ni Jonathan fẹran?

Lara awọn ounjẹ ti Jonathan fẹran julọ ni kabeeji, kukumba, karọọti ati eso apu.

Jonathan dun un wo loju nigba to wa ni kekere.

Niṣe lo maa n ṣere kaakiri labẹ tabili l'asiko tawọn eeyan ba n mu "tea."