You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alaafin Oyo's wives: Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
Lọjọ Abamẹta ni iroyin jade si igboro aye ti okiki si kan pe opo ti yẹ laafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta ti waja.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
Nigba to wa loke eepẹ ko to d'oriṣa, awọn arẹwa olori kii ṣọwọn laafin Adeyẹmi Alaafin Ọyọ, eyi lo si n mu ki ọpọ maa ṣe ibeere lori ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn olori wọnyii ti ọpọ maa n pe ni 'Ẹ̀lẹ̀ Daddy' lori ayelujara.
- Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ síwájú lẹ́yìn tí afurasí kan tó lọ́wọ́ nínú ikú Timothy Adegoke ṣubú nílé ẹjọ́
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn olòrì Alaafin Adeyemi àtàwọn tó bá fẹ́ fẹ́ wọn
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France
- Okùnrin tó so àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́, tó sì nà wọ́n rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he
Koda awọn iroyin kan tilẹ gbe e pe pupọ awọn ọkunrin to lọ si aafin ni lilọ ati daro ni wọn n lọ lati ṣẹju oge si awọn olori kekeke naa.
BBC News Yoruba tọ awọn agba lọ fun ilanilọyẹ lori ọrọ yii, ki gan an ni yoo ṣẹlẹ si awọn olori Alaafin lẹyin ti opo Adeyẹmi yẹ lọjọ Abamẹta?
Wọn gbọdọ ṣe oro mu ọwọ Alaafin kuro lara awọn olori ki ẹnikẹni to lee fẹ wọn - Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, Araba Ilu Osogbo
Baba Araba ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe awọn to n ti n sare naju oge si awọn olori ko ni suuru ni.
Oloye Ẹlẹbuibọn ni lasiko yii, ile opo lawọn Olori gbogbo yoo ṣi wa, o si di ẹyin igba ti wọn ba pari gbogbo oro ki wọn to lee sọrọ fifẹ tabi ko ṣe fifẹ.
Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe lootọ awọn olori to ba fẹ lọni ọkọ miran lee ṣe bẹ o ṣugbọn o ni ilana ti iṣẹṣe la kalẹ fun iru igbesẹ bẹẹ.
"Olori lẹtọ. Ọba maa n fi olori silẹ laafin ni, to jẹ wi pe ọba miran yoo tun de ba wọn laafin ti yoo si maa ṣe ọkọ wọn; ṣugbọn to ba si wu u o le lọ lọkọ nibomiran,
- Àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán afurasí tó ń pèsè àdó olóró fún IPOB
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France
- Òrumọ́jú ní ara Oba Lamidi Adeyemi wọ káà ilẹ̀ lọ ní Báárà gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìran Yorùbá ṣe làá kalẹ̀
Èyí lohun tí Aisha Buhari sọ fáwọn olùdíje dupò ààrẹ ní Nàìjíríà níbi àpèjẹ ìṣínu Iftah tó pè
ṣugbọn wọn o tilẹ ṣi pari oro naa, wọn o mu ọwọ Alaafin to wa nibẹ kuro lara wọn."
Baba Araba ilu Oṣogbo ni ẹyin eyi ni wọn to lee ṣe ohun to ba wu wọn ati pe lọwọ yii ko tii si ẹni to le sunmọ wọn.
Ẹnikẹni to ba n ṣẹju si awọn olori Alaafin bayii fẹ firu ko ina ni - Fagbenle Adedayọ, Agẹṣin Adimula ilu Ila Ọrangun
Oloye Fagbenle Adedayọ,Agẹṣin Adimula ilu Ila Ọrangun paapaa ṣalaye siwaju pe ẹni to ba mọ pe 'oun ko lori meji ko gbọdọ maa sare lọmaa du iyawo ọba.'
Ninu alaye ti Oloye Fagbenle Adedayọ to tun jẹ ọkan lara awọn afọbajẹ ilu Ila Ọrangun sọ fun BBC News Yoruba, yatọ si awọn ọba ti ko ba ṣoro ọba nilẹ Yoruba, ko si ọba ti yoo fẹ iyawo sile ti wọn ko ni kọkọ ṣe oro fun un ko to wọ ọdẹdẹ kabiyesi naa lọ.
O ni bi wọn ko ba ṣi iru oro bẹẹ kuro lori iyawo naa, ko si ọkunrin kan to gbọdọ ni oun fẹ gbe igbesẹ ati sunmọ iru obinrin bẹẹ.
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- 'Èèwọ̀! Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ajá mọ́'
- Okùnrin tó so àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́, tó sì nà wọ́n rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he
- Emmanuel Macron borí Le Pen ní ìbò ààrẹ France
- Wàhálà ṣẹlẹ̀ nípìnlẹ́ Ondo nítorí ẹ̀sùn pe ọlọ́pàá ṣòkùnfà ikú èèyàn méjì àti Báàlẹ̀ ìlú