Yoruba kings that died recently: Alaafin, àti ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré

Gbogbo awọn ọmọ ilẹ kaarọ, o jiire, lo ti n sẹ lede lẹyin Alaafin ilu Oyo, to waja, Oba Lamidi Adeyemi.

Oru mọju ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, ni Alaafin tẹri gbaṣọ, lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.

Ṣugbọn ṣaaju iku rẹ, ko din ni ọba alaye marun-un mii lo ti tẹrigbaṣọ laarin oṣu marun-un si asiko yii, ti iku wọn si n ka awọn ọmọ ilẹ Yoruba lara.

Soun ti Ogbomoso, Oba Jimoh Oladunni Oyewumi

Ọba, Alhaji Dr. Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade Kẹta, rewalẹ aṣa, ni ọjọ aiku, ọjọ Kejila oṣu Kejila ọdun 2021 lẹni ọdun marundinlọgọrun.

Ọdun 1926 ni wọn bi Soun si idile Bello Afolabi Oyewumi Ajagungbade II ati Ayaba Seliat Olatundun Oyewumi.

Oke Padre ni St Patrick Primary School ni Soun ti ka ile ẹkọ alakọbẹr laarin ọdun 1932-1938.

Ni 1938 Soun kawe ni Ogbomosho Peoples Institute to ti wa pada wa di Ogbomosho Grammar School.

Soun ko ribi tẹsiwaju nidi ẹkọ rẹ eyi to mu ki o bẹrẹ iṣẹ aṣọ ofi eyi to gbe de awọn ilu bi Ilesa ati ibomiran.

Soun Ogbomoso da ileeṣẹ tirẹ silẹ to pe orukọ rẹ ni J.O Oyewumi and Co ni ọdun 1967.

Ileeṣẹ yi gbooro debi pe Soun pẹka sidi ile tita ati eto inaju to si di gbajugbaja oniṣowo.

Ọdun 1973 lo gun ori oye gẹgẹ bi Soun Ogbomoso to si lo ọdun mẹtadinlaadọta lori oye.

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oba Saliu Adetunji

Oba Saliu Adetunji ti darapọ mọ awọn Baba nla rẹ ni ajule ọrun, lẹyin to ku si ilewosan aladani kan nilu Ibadan ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2022.

Ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun ni.

Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2016 ni wọn fi Ọba Adetunji jẹ gẹgẹ bi olubadan kọkanlelogoji.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 1928 ni wọn bi Oloogbe Saliu Akanmu Adetunji ni agboole Adetunji, ni augbo Popoyemoja nilu Ibadan.

Gẹgẹ bi eto ọba jijẹ nilẹ Ibadan, ọdun 1976 ni Saliu Akanmu Adetunji di Mogaji agboole Adetunji.

Akasọ oye mẹtalogun lo gun ko to o di Olubadan lọdun 2016, lẹyin ti Oba Samuel Odulana waja.

Gbajugbaja oniṣowo to n gbe rẹkọdu orin jade ni Oba Adetunji.

Lara awọn olorin to gba ileeṣẹ Omo Aje Records jade ni Dauda Epo Akara, Tatalo Aremu, Amuda Agboluaje, Wasiu Ayinde K1, Jimoh Ayinla Anikura, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Olowu ti Owu, Oba Olusanya Dosunmu Amororo Keji

Olowu ti Owu nipinlẹ Ogun, Oba Olusanya Dosunmu Amororo Keji papoda, ni ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2021, lẹyin aisan ọlọjọ diẹ.

Ọdun 2005 ni Oba Dosunmu jẹ ọba, lẹyin ti Oba Adisa Odeleye waja lọdun 2003.

Oṣiṣẹ ijọba ni, to si jẹ gbajumọ agbohunsafẹfẹ. Oun lo jẹ olootu gbajugbaja ere agbelewo, Village Headmaster.

Oun ni Olowu kẹtala to jẹ

Iroyin ti ak o le fidiẹ mulẹ sọ pe Oba Dosunmu, sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe oun ko ṣe ẹbọ tabi etutu kankan ṣaaju ki oun to jẹ ọba, gẹgẹ bi aṣa ilẹ Yoruba.

O ni iru awọn nkan bẹẹ ko ba ode oni mu.

Onikoyi ti Ikoyi-Ile, Oba Abdulyekeen Ayinla Oladipupo Kẹrin

Oba Abdulyekeen Ayinla Oladipupo Kẹrin, Onikoyi ti Ikoyi Ile nipinlẹ Oyo, waja ni ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2022.

Iroyin sọ pe kabiyesi darapọ mọ awọn baba nla wọn niwalẹ aṣa, lẹyin aisan ranpẹ.

ṣaaju iku Oba Oladipupo, oun ni alaga igbimọ lọbalọba nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo.

Ọdun 2006 lo gba ade gẹgẹ bi Oba.

Asigangan ti Iganga, Oba Abdul-Azeez Adewuyi Aribiyan

Ko ju ọjọ mọkanla lọ lẹyin iku Soun Ogbomoso, Oba Oyewumi, ti oba ilu Igangan, Kabiesi Abdul-Azeez Adewuyi Aribiyan, waja.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021, lo mi eemi igbẹyin.

Ilu Igangan to jẹ ọkan pataki lara awọn ilu to wa ni agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, di gbajugbaja lasiko ti awọn afurasi Fulani n doju ogun kọ awọn ara ilu naa.

Asiko naa bakan naa, ni ajijagbara fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Sunday Igboho, tubọ di ilumọọka, nitori bo ṣe lọ koju awọn Fulani naa nilu Igangan.