You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Soun Ogbomoso's daughter dies: Ikú tó mú Soun Ogbomosho tún ti mú àkọ́bí rẹ̀ lọ o!
Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole, tó jẹ́ àkọ́bí lóbìnrin fún olóògbé Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Oyewumi Ajagungbade ti dágbére fáyé.
Àdánu yìí wáyé ní bí ó ṣe kù sáátà kí ó pé oṣù kan tí bàbá rẹ̀ re ìwàlẹ̀ àṣà.
Nigba ti BBC Yoruba kan si Aafin Soun, oṣiṣẹ kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ jẹ ko di mimọ pe lootọ lo ṣẹlẹ.
- Aare Muhammadu Buhari ránṣẹ́ sí ìlú Ogbomoso lórí ikú Soun
- Wo ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa ìgbésí ayé Ọba Ajagungbade Ogbomosho tó wàjà
- Irọ́ ni pé àwòrán CCTV ṣàfihàn bí Ramon Adedoyin ṣe pa Timothy Adegoke - Agbẹjọ́rò Adedoyin
- Gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí kò bẹ̀rẹ̀ sáà ètò ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ kẹrin oṣù Sẹẹrẹ la ó ti pa - Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwòrán Raheem Adedoyin léde láwọn ìwé ìròyìn lórí ikú Timothy Adegoke
Ọdún mọ́kànléláàdọ́rin ni Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole lò lókè èèpẹ̀ kó tó jẹ́ Ọlọ́run ní pè.
Ṣaaju ki Oba ilu Ogbomosho yii ku naa lo ti kọkọ padanu ọmọ rẹ ọkunrin kan.
Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lábẹ́ ìjọba ológun kú sí ìlú Ìlọrin lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.
Iroyin ni, olukọni ni Arabinrin Taibat jẹ ni ile ẹkọ giga Fasiti ti ilu Ilorin.
Ọjọ̀gbọ́n Taibat Danmole ni wọ́n ti sin ní ìlànà Mùsùlùmí.