Alaafin Oyo: Wo ohun tí o kò mọ̀ nípa Morenikeji Lasisi, olórí ẹrú tó ti bá Aláàfin mẹ́ta ṣiṣẹ́

Morenikeji Lasisi olori gbogbo eru ni afin oba Oyo ti sin Oba meta.

O ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ẹrú láti ọdún 1945 títí di àkókò yìí

Lasisi ti sìn fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin.

Kini a mọ́ nipa Lasisi Morenikeji?

Ohun ti BBC ri kojọ nipa Lasisi ni pe baba agba yii ti lè ni ẹni ọgọ́fà ọdún bo tilè jẹ wí pé a ko tii le fidi ọjọ ori rẹ ni pato mulẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii.

Sugbon Lasisi ni wọn n pe ni Baba Kekere laafin Oyo.

Awọn Alaafin wo ni Lasisi ti ba ṣisẹ ni Aafin Oyo?

Baba Kekere Aafin Oyo ni ọpọ maa n pe Lasisi Morenikeji.

O ti ba Oba Adeniran Adeyemi keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1945 si ọdun 1956

Bakan naa ni Lasisi ba Oba Gbadegeshin Ladigbolu keji ṣiṣẹ laarin ọdun 1956 si ọdun 1968 sise.

Leyin naa lo tun jẹ olori gbogbo ẹru ni aafin ni asiko Oba Lamidi Adeyemi keta laarin ọdun 1970 si ọdun 2022.

Iru iwa wo ni Lasisi ni l'Aafin Oyo?

Lasisi Baba Kekere ni ọpọ ni aafin Oyo sapejuwe gẹgẹ bi oniwa tutu eeyan

Opọ sọ pe onirẹle ti awọn olugbe aafin maa n finu tan ni Lasisi jẹ.

Ati pe nitori pe kii ṣe ẹni to tobi tabi sanra, ọpọ kii tete mọ nipa rẹ ni eyi to mu orukọ inagijẹ Baba Kekere fun un.

Wọn ni Baba kekere kii binu nitori pe o gab pe, agba ti ko binu ni ọmọ rẹ n pọ.

Wọn ni pe ko si ẹni to le sọ ọjọ ori Lasisi ni pato ṣugbọn ọpọlọ rẹ kun fun imó itan aafin ati awọn ori ade gbogbo ni Oyo.

Iwadii BBC fihan pe Lasisi ti le ni ọgọrun un ọdun.