Aheregbe and Amole festival in Akure: Ojú aráàlú rí màbo pẹ̀lú báwọn jàǹdùkú ṣe sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure

Ibinu ati ẹhonu lo tẹle ayẹyẹ ọdun Amọle, iyẹn ọdun iṣẹṣe ilu Akurẹ to waye lọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2021.

Gẹgẹbi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ kaakiri awọn agbegbe ilu Akurẹ lasiko ọdun naa ṣe sọ, ọpọ iwa ole, ijinigbe ati idaluru lo waye lasiko ọdun naa ti awọn janduku kan si n fọwọ lalẹ pe awọn lẹtọ lati ṣe bẹ labẹ iboju ọdun naa.

Fun apẹrẹ, lasiko ajọdun naa, nṣe lawọn janduku kan kọlu awọn eeyan lagbegbe Bọlajoko Junction ni Oke Aro ni opopona Idanre. Awọn janduku naa di ọna mọ ọkọ bọọsi kan to ko ounjẹ atawọn ohun elo ile miran ti wọn si ji gbogbo ohun to wa ninu rẹ lọ.

Bakan naa lawọn oju mi too kan tun ṣalaye ohun ti oju ri awọn janduku kan ti wọn ni awọn n fi idi 'ofin maa ta ọja" ti aafin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pa pe ko gbọdọ si ṣiṣi ọja lọjọ ọdun Aheregbe ati Amọle naa mulẹ ni ṣe fi tipa gbe ọmọ okunrin aṣoju ileeṣẹ itaja kan ti wọn si tun jo taya ọkọ rẹ.

Okunrin naa gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle kan nilu Akurẹ ṣe sọ, arakunrin naa n gbe ọmọ rẹ lọ sileewe lasiko ti awọn janduku naa da lọna ti wọn si ko gbogbo ọja ileeṣẹ rẹ to ko sinu ọkọ.

Gbogbo bi arakunrin naa ṣe n pariwo pe oun ko ta ọja, ọmọ oun loun n gbe lọ sileewe ko tu irun kan lara awọn eeyan naa, koda wọn tun gbe ọmọ rẹ naa pẹlu. Awọn aladugbo lagbegbe naa lo fariga tẹle awọn janduku ọhun lati gba ọmọ rẹ pada.

Ni Ọjọru ni atẹjade kan jade lati afin Ọba Deji ti ilu Akurẹ pe ayẹyẹ ọdun aheregbe ati amọle yoo waye, nitorina ki wọn ọja ati ṣọọbu ko wa ni titi pa. Amọṣa atẹjade naa ko sọ pe ki ẹnikẹni o maa jade tabi rin loju popo.