Gani Adams: Kò dín ní ₦3 bílíọ̀nù tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Yoruba ti san fún àwọn ajínigbé láàrín ọdún méjì sẹ́yìn

Aarẹ Ona Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ pe ko din ni biliọnu mẹta naira ti awọn eeyan apa Iwọ-oorun Naijiria ti san fun awọn ajinigbe laarin ọdun meji sẹyin.

O fi kun pe nnkan bii igba eeyan ni awọn ajinigbe ọhun ti ṣekupa laarin ọdun meji yii kan naa.

Aarẹ Ona Kakanfo lo sọ ọrọ naa nibi ipade eto abo ilẹ Yoruba kan to waye niluu Abeokuta.

O ni ko si iroyin nipa ijinigbe to maa n waye nilẹ Yoruba ti wọn ki n bu oun gbọ.

Gani Adams juwe ipade naa gẹgẹ bii eyii ti yoo fun gbogbo awọn ti orọ naa kan lanfaani lati jọ ṣiṣẹ papọ.

O ni "Gẹgẹ bii Aarẹ Ona Kakanfo, o ni awọn iroyin kan ti mo maa n gbọ to jẹ pe awọn ileeṣẹ eto abo mii gan kii gbọ si."

"Ni gbogbo igba ti nnkan ba ti ṣẹlẹ nibikibi, wọn maa n pe aago mi ti wọn a si bere lọwọ mi igbeṣe ti mo fẹ gbe lati yanju rẹ."

"Ṣugbọn o ṣeni laanu pe mi o ni agbara lati ṣe bii awọn Aarẹ Ona Kakanfo aye atijọ, ṣugbọn mo ṣe iwọn ti mo le ṣe gẹgẹ bii Aarẹ."

Gani Adams ni ohun ibanujẹ nla ni pe awọn ọdaran Fulani n ṣe bo ṣe wu wọn nilẹ Yoruba, ati pe ti awọn ijọba ilẹ Yoruba ko ba ji giri si ojuṣe wọn, o ṣeeṣe ki igbẹyin ilẹ Yoruba da bi ti oke ọya.

Lẹyin naa lo ke si ijọba apapọ lati fi oju ṣunukun wo ọrọ ijọba ẹlẹkunjẹkun ti awọn ti pariwo lati ọjọ pipẹ gẹgẹ bii ọna abayọ si eto abo to dojuru.

O ni "Ti ẹba ṣe iṣiro iye owo itusilẹ ti awọn eeyan agbegbe Oke-Ogun, Ibarapa, Ekiti, Akoko ati Yewa ti san fun awọn ajinigbe, yoo ti le ni biliọnu mẹta naira."

"Ti ẹ ba si ṣe iṣiro awọn ti wọn ti pa danu, wọn ti maa le ni irinwo, nitori naa o yẹ ki ijọba gbe ọrọ ijọba ẹlẹkunjẹkun yẹwo."