Mercy Aigbe: Mo bó ní kókósẹ̀, orúnkún àti apá lẹ́nú iṣẹ́, ìrora náà pọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Agba adura ni pe ohun ta jẹ la n wa, ka ma pade ohun ti yoo jẹ wa.

Adura yii lo gba pupọ fun agba osere tiata lobinrin kan, Mercy Aigbe lasiko to ni ijamba ẹnu isẹ nigba to n ya sinima kan laipẹ yii.

Mercy, ẹni to salaye bi ijamba naa se waye ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ, ni ọpọ egbo ni oun gbe lasiko ti ijamba naa waye.

O ni oun bo lẹsẹ pupọ lasiko ijamba naa, ti oun si tun fi apa bo pẹlu eyi to waye nigba ti n ya sinima naa.

Yoruba ni ti ẹsin ba da ni, a tun gun ni. Eyi si lo mu ki Mercy kede pe oun dupẹ pe ijamba naa ko ju bayi lọ, o si to fun iru sinima ti oun fẹ gbe jade lati ipasẹ rẹ.

"Ijamba ẹnu isẹ ni, mo ni aimọye egbo lasiko ti mo n ya sinima kan, mo bo ni kokosẹ pupọ, koda, n ko ti le rin daadaa.

Amọ o to bẹẹ, o ju bẹẹ lọ ti n ba ro bi sinima naa ti kanka to. Isẹ ta yan laayo, la n se. A ko si ni owo meji, a gbọdọ se ni."