You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lai Mohammed: Ṣé mo jọ ẹni tó gba Benin Republic sá kúrò ní Nàìjríà ni, Lai Mohammed fèsí sí ìróyín pé Ó yọ́ kẹ́lẹ́ kúrò ní Nàìjíríà
Minisita fun ọrọ iroyin ati aṣa lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Lai Mohammed ti sọ pe irọ ko si idi kan fun oun lati daṣọ bori kuro lorilẹede Naijiria bi ẹni "to gba orilẹede Benin Republic sa kuro lorilẹede"
Ni Ọjọru ni iroyin kan jade sita pe Minisita fọrọ iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ti kuro lorilẹede Naijiria ati pe o yọ kẹlẹkẹlẹ lọ si orilẹede Amẹrika ni lati lee lọ ṣe ipade pọ pẹlawọn alaṣẹ ileeṣẹ oju opo ikansiraẹni Twitter.
Amọṣa ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ akoryinjọ NAN, Lai Mohammed ni iroyin ofege lasan ni iroyin naa nitoripe gbogbo ọna to yẹ ki eeyan rin lati rinrinajo kuro ni Naijiria ni oun rin ki oun to wọ baluu.
- Gbogbo ṣọ́ọ̀bù àti ọjà yóò wà ní títì pa nílùú Akure nítorí ọdún Ahérégbé àti Amólè
- Ṣé lóòtọ́ lòṣìṣẹ́ 'Immigration' gbé ìgbájú fún alága káńsù nílùú Ibadan?
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
Bakan naa lo fi kun un pe oun ko tori Twitter wa si Amẹrika bikoṣe lati ṣe ipade pẹlawọn ileeṣẹ iroyin agbaye gbogbo nipa ọkan-o-jọkan ilakaka ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari lati koju igbesumọmi ati awọn agbebọn pẹlu ajinigbepawo ni Naijiria.
O ni iroyin ti iwe iroyin naa gbe jẹ apẹrẹ kan gboogi nipa ewu ayederu iroyin ati ijamba ti o lee mu ba orilẹede bi igbesẹ to yẹ ko ba waye lori gulegule awọn oju opo ayelujara.
"Nigba ti wọn sọ pe mo yọ kẹlẹkẹlẹ kuro ni Naijiria, ṣe wọn fẹ sọ pe papakọofurufu ti ẹnikẹni ko si ni mo ti wọ ọkọ ofurufu ni abi boya mo rinrinajo lọ si Benin republic lati gba ibẹ kuro ni Naijiria?"
Lai Mohammed ni papakọ ofurufu agbaye ti gbogbo eeyan n lo ni oun pẹlu lo, ti oun si ṣe gbogbo eto irinna to yẹ nitori naa ko si idi fun ẹnikẹni lati sọ pe oun daṣọ bori kuro ni Naijiria.
Ijọba orilẹede Naijiria ati ileeṣẹ Twitter ṣi n jiroro lori ọna ati pada sẹnu iṣẹ rẹ lẹyin ti ijọba fi ofin dee lẹyin to yọ atẹjade kan ti ileeṣẹ aarẹ fi sita.
Bi o tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ni igbesẹ naa ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu yiyọ atẹjade aarẹ danu bikoṣe nitori iṣọkan orilẹede Naijiria, ọpọlọpọ awọn onwoye lo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti ijọba Naijiria gbe lori ọrọ naa.