You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olusegun Obasanjo diabetes: Ó ti lé ní ọdún 35 tí mo ti ní àìsàn ìtọ̀ súgà- Olusegun Obasanjo
Aarẹ Naijiria nigba kan, Olusegun Obasanjo ti sọ pe o ti le ni ọdun marundinlogoji ti aisan itọ ṣuga ti na oun finra.
Nibi eto kan to waye nipinlẹ Ogun ni ọjọ Ọjọbọ, lori aisan itọ ṣuga, ni Obasanjo ti sọ ọrọ naa lati gba awọn ọdọ to ni aisan ni imọran pe kii ṣe aṣekupani.
O ni "o ti le ni ọdun marindinlogoji ti mo ti ni aisan itọ ṣuga, emi naa si re e niwaju yin. Mo n rin kiri, mo n fò, mo n ṣe oriṣiriṣi nkan ti ọpọ eeyan to jẹ ọjọ ori mi ko le ṣe."
Obasanjo sọ pe aisan ọhun ti pa pupọ lara awọn ọrẹ oun.
"Lati igba ti mo ti ni itọ ṣuga, ọpọ awọn ọrẹ mi lo ti ku, idi si ni pe wọn ko mojuto aisan naa bo ṣe yẹ ki wọn o moju to o. Ipele ti aisan itọ ṣuga rẹ ko ni nkankan ṣe e pẹlu itọju, nitori pe ko ti i si iwosan fun aisan naa."
O ni o ṣe koko pe ki ẹni to ba ni aisan itọ ṣuga ṣọra fun awọn ounjẹ kan, paapaa eyi to ba ni ṣuga. O ni o yẹ ki ẹni to ba ni i ma a jẹ odiwọn kekere fun ounjẹ to ni ṣuga ninu 'carbohydrate'.
Ẹ má ṣe alai lo oogun yin, insulin, ati abẹrẹ.
"Mo ma n gbe awọn oogun mi lọ si gbogbo ibi ti mo ba n lọ, mo si ma n yẹ ibi ti ṣuga inu ẹjẹ mi de duro wo ni gbogbo igba."
Aarẹ nigba kan ri ọhun sọ pe lootọ ni aisan itọ ṣuga ko ni iwosan kankan. ṣugbọn o ṣe e mojuto.
Ki lo n fa aisan itọ ṣuga?
Oriṣi aisan itọ ṣuga meji lo wa. Eyi ti awọn onimọ iṣegun oyinbo n pe ni Type 1 ati Type 2.
Aisan yii ma n bẹrẹ nigba ti nkan ba ṣe eroja 'insulin'to ma n pin glucose (suga) fun awọn ẹya ara.
Ti ounjẹ ba ti dà ninu ara, to si wọ inu ẹjẹ lọ, eroja insulin ni yoo yọ glucose jade nibẹ, ti yoo si pin kaakiri ẹya ara, lati fun ni okun.
Ṣugbọn ti eeyan ba ni aisan itọ ṣuga, ara rẹ ko ni i le sọ glucose di okun. Idi ni pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe eroja insulin ko to o, tabi ki insulin to wa ninu ara ko ṣiṣẹ daadaa.
Type 1: Fun ẹni to ba ni ipele aisan itọ ṣuga yii, awọn ẹya ara to jẹ 'sọja'(immune system) yoo ma a kọju ija si awọn ẹya to n ṣe insulin.
Type 2 - ara ko pese insulin to to, tabi ko jẹ pe insulin to n jade ko ba ara mu.
Iru igbaye ti eeyan n gbe le mu adinku ba type 1.
Sugbọn fun type 2, jijẹ ounjẹ to dara, ere idaraya ati ki eeyan o ma sanra ju, jẹ ọna ti wọn n gba mojuto o.