Diabetes - Kí ló ń fa àìsàn ìtọ̀ súgà?

Aisan itọ ṣuga jẹ odu lawujọ ọmọniyan lagbaye; yala laaarin mẹkunu tabi ọtọkulu, olowo tabi talaka.

Aisan itọ ṣuga eyi ti oloyinbo mọ si Diabetes jẹ aisan ti o lagbara pupọ ti o si jẹ aisan ọlọjọ pipẹ eleyi ti o nii ṣe pẹlu iye eroja adun ṣuga ti o wa ninu ẹjẹ eniyan nipasẹ eroja gulukoosi ninu agọ ara.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Irufẹ aisan itọ ṣuga wo lo wa?

Irufẹ aisan itọ ṣuga mẹrin lo wa; ṣugbọn Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, oniṣegun oyinbo kan, Dokita Ọlamoyegun ṣalaye pe meji ninu wọn ni o jẹ ilu mọọka.

  • Aisan itọ ṣuga onipile akọkọ ti a mọ si Type I: Aarin awọn ọmọde ni eleyi ti wọpọ. Gẹgẹ bi Dokita Ọlamoyegun ṣe sọ, "awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn wa ni aarin ọdun mẹta, mẹwa, ki a saa sọ pe awọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọgbọn ọdun lọ."
  • Aisan itọ ṣuga onipile keji ti a mọ si Type II: eyi ni o jẹ gbajugbaja julọ laarin awọn aisan itọ ṣuga to wa lagbaye. Laarin awọn eeyan ti ọjọ ori wọn ko ju ogoji ọdun si ọgọta ọdun ni eyi ti maa n waye.
  • Aisan itọ ṣuga miran ni ti inu oyun ti oyinbo n pe ni gestational diabetes: asiko ti obinrin ba wa ninu oyun ni wọn maa n ri eleyi. Irufẹ obinrin bẹẹ lee maa ni tẹlẹ ri ṣugbọn ko jẹ asiko ti o ba wa ninu oyun ni yoo ṣa dede jẹyọ.
  • Aisan itọ ṣuga to nii ṣe pẹlu awọn aiṣedede miran lagọ ara. Fun apẹrẹ, ' awọn oogun kan wa fun lilo ti o maa n fa aisan itọ ṣuga tabi awọn aiṣedede miran ni agọ ara.'

Kini o nfa aisan yii?

Oniruru ni ohun to lee fa itọ ṣuga. Lara ohun ti awọn onimọ bii Dokita Ọlamoyegun ati ajọ eto ilera agbaye fi sita ni ajogunba eleyi ti o lee waye bi ẹnikẹni ninu ẹbi eniyan bẹẹ ba ni.

  • Awọn ohun ti eniyan njẹ tabi mu pẹlu lee faa.
  • Ẹjẹ riru lee fa aisan itọ ṣuga. Gẹgẹ bi awọn onwoye ṣe sọ, bi ibeji ni aisan ẹjẹ riru ati itọ ṣuga. O wọpọ lati ri ẹni ti o ni ẹjẹ riru lai ni itọ ṣuga tabi ni itọ ṣuga lai ni ẹjẹ riru.
  • Bakan naa ni bi ọra ba pọ ju lara, iyẹn ara sisan ju pẹlu lee fa aisan itọ ṣuga.