You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aheregbe festival: ọdún Ahérégbé àti Amólè bẹ̀rẹ̀ lónìí l'Akure, Déjì ní kí wọ́n tí gbogbo ọjà pa
Ọdọọdun ni ọdun Ahérégbé àti Amólè maa n waye nilu Akure ti tọdun yi ko si yatọ si tatẹyinwa.
Niṣe lawọn araalu bọwọ fun aṣẹ ti Deji pa pe ki wọn ma ṣe ṣi ṣọọbu itaja.
Die ree ninu awọn aworan binkan ti ṣe lọ nibi ọdun yi ni Akure.
Paroparo lawọn ile itaja ni Ọja Oba ti tẹlẹ da ti ko si si karakatra kankan to n waye nibẹ.
Ki gbogbo nkan baa le lọ leto leto, awọn eeyan kan a maa kaakiri lati ri pe awọn eeyan tẹlẹ aṣẹ yi.
Ẹnikẹni ti wọn ba ri to ṣi ṣọọbu, wn a maa ko ọja rẹ ti ko si ni si nkankan ti yoo tẹyin rẹ bọ.
Lara awọn eto to maa n waye nibi ọdun naa ni pe awọn ijoye yoo ṣe abẹwo si Deji ilu Akure.
Gbogbo ṣọ́ọ̀bù àti ọjà yóò wà ní títì pa nílùú Akure nítorí ọdún Ahérégbé àti Amólè
Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi ti ni ki wọn ti gbogbo awọn ile itaja ati ṣọọbu to wa nilu naa nitori ọdun Aheregbe ati Amole ti yoo waye.
Awọn ọdun naa yoo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021, ati ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 yii kan naa .
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ori ade naa, Adeyeye Michael fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni igbesẹ naa ṣe pataki ki wọn le raye ṣe ọdun naa to maa n waye lọdọọdun.
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú èèyàn méje nínú ẹbí kan
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
- Fadá wọ gàù torí pé ó 'kiss' akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ta lọ́jọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde
Lasiko ọdun ọhun ni awọn agbagba ilu Akure maa n gbadura fun alaafia ilu naa, to fi mọ ilu Oba Ile, eyii ti ko fi bẹẹ jina si Akure.
Ko ni si kata-kara ninu awọn ilu memeji lasiko ti ọdun Aheregbe ati ọdun Amole yoo maa waye.
Ẹnikẹni to ba taja ni ayajọ ọdun naa le padanu ọja rẹ nitori awọn to n kaakiri ilu lati ri daji pe ọdun naa bo ṣe yẹ ko lọ le ko ọja irufẹ ẹnio bẹẹ.
To n tumọ si pe awọn to n kaakiri naa laṣẹ labẹ aṣa ilu Akure lati ko tabi gbẹsẹ ọja irufẹ oniṣowo bẹẹ.
Bakan ni ilu yoo ko iṣọwọ awọn miran si aarin igboro pẹlu paṣan lọwọ ti wọn a si maa ko paṣan bo ẹnikẹni to ba tapa si ilana to rọ mọ ọdun ọhun, bii ṣiṣi ṣọọbu.
- Èyí lohun tí Amòfin àgbà Nàìjíríà, Malami sọ níléẹjọ́ lónìí nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu Fulani àti ìkọlù tó wáyé nílé Igboho
- Gómìnà ìpínlẹ̀ kan rèé tó ní kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn
- "Ìgbẹ̀yìn Naijiria yóò burú ju ti Afghanistan lọ tíjọba kò bá dẹ́kun ẹlẹ́yàmẹ̀yà"
- Oní Típà tó bá ta yanrìn ní iye owó tí a kò fọwọ́ sí yóò fojú balé ẹjọ́ - Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo
Ṣaaju ni oloye Aṣamọ ti ilu Akure ti kọkọ sọ fun awọn akọroyin pe ọdun naa ṣe pataki niluu Akure ki alafia le jọba ninu ilu naa.
O fi kun pe ko pọju ti wọn ba ya ọjọ meji pere sọtọ laari n ọdun kan lati ṣe ọdun fun alaafia awọn araalu.
- Nígbà tí mo darapọ̀ mọ́ Nollywood, gbogbo ọkùnrin ló fẹ́ bámi ní ìbálòpọ̀
- Ẹ̀gbọ́n tó jẹ́ arọ, bàbá tí kò lẹ́sẹ̀, ọ̀pọ̀ ìyàwó àti ọmọ ni àbúrò mi tí wọ́n pa ní Jos fi silẹ́ ní Ondo
- Ìjọba ṣetàn láti yá N4.89tn fún ètò ìṣúná ọdún 2022
- Wo kókó márùn-ún nípa òfìn tuntun lórí eporọ̀bì tí Buhari buwọ́lù àti bó sẹ kàn ọ́
- 'Gbogbo ṣọ́ọ́bù tí mo ti n ta 'frozen chicken' ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn dáná sun ní Mushin'