You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PIB bill meaning: Àwọn nkan tó yẹ láti mọ̀ nípa òfin eporọ̀bì tí Ààrẹ Buhari buwọ́lù
Ofin tuntun lori eporọbi ti Aarẹ Buhari buwọlu ni ọjọ Aje, PIB 2020 jẹ ofin ti ireti wa pe yoo mu awọn atunto kan waye ni ẹka eporọbi ni Naijiria ati afẹfẹ gaasi.
Ọdun 2008 ni wọn kọkọ gbe kalẹ niwaju ile aṣofin apapọ, ki Aarẹ Muhammadu Buhari to o buwọlu lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹjọ.
Ọpọlọpọ ofin to wa fun eporọbi ni Naijiria lo ti wa lati ọdun 1969, eyi to tumọ si pe wọn ko fi bẹẹ ba asiko yii mu mọ.
1. Ofin tuntun yii yoo mu ayipada ba akoso ati ilana ti ajọ NNPC fi n ṣiṣẹ, yoo si tun mu idagbasoke ba awọn ilu ti wọn ti n wa eporọbi.
Ofin naa yoo ṣe idasilẹ amojuto to koju osunwọn , ṣiṣe iṣẹ ni ọna to tọ, nipa ṣiṣe alakalẹ ojuṣe awọn oṣiṣẹ eporọbi ati ileeṣẹ, ti yoo si mu ki awn to n wa eporọbi tẹle ilana to yẹ.
Bakan naa ni yoo tun sọ ajọ NNPC di eyi ti yoo ma a pawo wọle lọna yanturu.
2. Amojuto
Ọkan pataki lara afojusun aba ofin naa ni lati ṣe igbelarugẹ wiwa ati tita eporọbi ni Naijiria fun anfaani awọn ọmọ Naijiria, ati lati mu idagbasoke to poju owo ba ẹka eporọbi.
Bakan naa ni yoo tun ri i daju pe aabo to peye wa ninu wiwa epo, gbigbe e lati ibi kan si ibomiran, akoyawọ ninu amojuto eporọbi ni Naijiria.
Yoo tun mu ki ifigagbaga wa lori iye ti awọn alagbata n ta epo bẹtiro ati gaasi, to fi jẹ pe onibaara le lọ si ibi to wu u.
3. Idagbasoke awọn ilu ti wọn ti n wa eporọbi
- Ọkan pataki lara nkan to tun wa ninu aba ofin tuntun yii ni pe yoo mu igbeaye idẹrun ati ọrọ ba awọn ilu ti wọn ti n wa eporọbi, paapaa lori eto ọrọ aje ati nkan amuludun.
- Ileeṣẹ yoowu ti ijọba ba fun ni iwe aṣẹ lati maa wa eporọbi gbọdọ ma a fun ilu to wa ni ìdá mẹta gbogbo owo to n pa lọdọọdun. Eyi jẹ afikun si ida mẹta to n fun ajọ to n mojuto idagbasoke Niger Delta, NDDC.
- Wọn yoo lo 75% owo naa fun akanṣe iṣẹ, wọn o fi 20% pamọ, wọn yoo si fi 5% ṣe amojuto ilu wọn.
- Ṣugbọn ṣa, ilu naa ko ni i gba ẹtọ rẹ ti wọn ba fọ ọpa epo tabi ba irinṣẹ awọn ile eporọbi jẹ.
4. Atunto ajọ NNPC
- Ajọ NNPC yoo di nkan ti awọn araalu le ra ipin idokowo si, dipo bo ṣe jẹ pe ijọba apapọ Naijiria nikan lo ni i tẹlẹ.
Sugbọn ijọba ni yoo ma a mojuto idokoowo naa.
- Bakan naa ni ofin naa sọ pe ki idasilẹ ajọ tuntun, Nigeria National Petroleum Corporation Limited, yoo waye.
- Ajọ yii ni yoo ma mojuto ẹka eporọbi, lai lọwọ ijọba ninu. Wọn yoo ma a gba owo ori, owo ilẹ, ati ipin to kan ijọba ati ara ilu.
5. Ilana tuntun ati ijiya fun awọn ileeṣẹ to n wa epo ni Naijiria
- Ofin tuntun naa tun ṣe agbekalẹ ijiya fun awọn ileeṣẹ eporọbi to ba kuna lati san owo ori, tabi parọ iye owo ti wọn pa wọle tabi padanu.
- Ni bayii, ajọ to n gba owo ori fun ijọba apapọ, FIRS, yoo ma a gba owo ori to wa laarin 15%-30% lori èrè tí àwọn ileeṣẹ ba ri lori wiwa epo. CIT 30% ati 2% owo ori fun eto ẹkọ.
- Milinu mẹwaa Naira ni owo itanran ti ileeṣẹ eporbi to ba kuna lati tete san owo ori rẹ yoo san ni ọj akọkọ. Yoo si san miliọnu meji Naira fun ọjọ kọọkan to ba tẹle.
Ofin tuntun yii ti bori ofin mẹwaa to wa nilẹ tẹlẹ fun ọrọ eporọbi ni Naijiria
Buhari buwọ́lu òfin àtúntò ẹ̀ka epo rọ̀bì, àwọn èèyàn Niger Delta yarí
Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu ofin ti yoo mu atunto ba ẹka epo rọbi ti wọn n pe ni Petroleum Industry Bill, PIB tọdun 2021.
Oludamọran si aarẹ Buhari feto iroyin, Femi Adesina lo kede bẹẹ fawọn akọroyin nigba to ni ayẹyẹ bibuwọlu ofin tuntun naa yoo maa waye lọjọru.
Adesina ni ofin atunto ẹka epo rọbi tuntun yii lo wa lati se agbekalẹ ilana ọtun fun ẹka epo rọbi ati idagbasoke awọn agbegbe ti epo rọbi ti n wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Taliban àti bí wọ́n ṣe gbàjọba ní Afganistan
- Ọwọ́ ti tẹ ogún afurasí lára àwọn tó pa àwọn arìnrìnajò láti ìpínlẹ̀ Ondo ní ìpakúpa ní Jos - Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá
- Wàhálà míràn tún bẹ́ sílẹ̀ ní Jos lẹ́yìn ìpànìyàn to wáyé lọ́jọ́ Satide
- Aṣòfin ọmọ ìpínlẹ̀ Ondo, Adedayo Omolafe "Expensive" ti jáde láyé
- FBI àti ìjọba Amẹ́ríkà tẹ ẹ̀tọ́ Nàíjíríà lójú lórí ẹ̀sún tó fi kan Abba Kyari
Ọjọ Kẹẹdogun osu keje ọdun 2021 ni ile asofin agba buwọlu ofin naa nigba ti ile asoju-sofin fontẹ lu lọjọ keji.
Haa, ọjọ buruku ni oni ti Buhari fontẹ lu ofin PIB - PANDEF
Wayi o, agbarijọpọ ẹgbẹ awọn eeyan agbegbe Niger Delta, PANDEF ti kede pe igbesẹ ti Buhari gbe, pẹlu bo se buwọlu ofin PIB naa, ko dara to.
Agbẹnusọ apapọ fun ẹgbẹ PANDEF, Ken Robinson lo kede bẹẹ pẹlu afikun pe "ọjọ ibanujẹ ati ọjọ buruku ni ọjọ oni jẹ lagbegbe Niger Delta ati Naijiria lapapọ.
Robinso, lasiko to n ba iwe iroyin Punch sọrọ ni bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan agbegbe Niger Delta tako igbesẹ naa, sibẹ aarẹ Buhari tẹsiwaju lati buwọlu ofin naa.
PANDEF lo ti kigbe saaju pe ida mẹwa owo tijọba ba n ri lati ara epo rọbi to n wa lagbegbe naa, ni ko maa fun awọn agbegbe ti epo naa ti wa.
Bakan naa lo yari lori ida mẹta ti ofin naa dabaa fun ijọba lati fun awọn agbegbe to n pese epo rọbi ninu owo to ba wọle lati ara epo naa.
"Eyi fihan pe ijọba Buhari ko naani ohun tawọn eeyan agbegbe Niger Delta n la kọja, awọn eeyan yii si lo n foju wina ayika wọn to ti bajẹ nitori epo ti wọn n wa nibẹ.
O se ni lanu pe lai naani bawọn araalu se pariwo to lori ida mẹta owo tasọrẹ ti ofin naa gbe kalẹ fawọn agbegbe ti epo rọbi ti n wa ati ida ọgbọn fun ileesẹ NNPC.
Ọna tawọn eeyan n gba sisẹ aje lo ti bajẹ, ta si n jiya nitori iwakusa epo rọbi lagbegbe wa, sibẹ ijọba ko naani wa, to si tun n gbe awọn ofin ti ko dara le wa lori.