Adedayo Omolafe Expensive ti jáde láyé

Oloṣelu ọmọ ipinlẹ Ondo to n ṣoju ẹkun Guusu ati Ariwa Akure nile aṣoju-ṣofin l'Abuja, Adedayo Omolafe, ti ọpọ mọ si Expensive ti jade laye.

Ẹnikan to sunmọ oloogbe naa sọ fun awọn akọroyin pe nnkan bii aago meji orumọju ọjọ Aje ni oloṣelu naa jade laye niluu Akure.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, oloogbe naa ko ṣaisan kankan ki ọlọjọ to de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Expensive ko ṣaisan, a ṣi jọ wa papọ laarọ ọjọ Aiku ni ki a to gbọ iroyin iku rẹ."

Expensive ni alaga ijọba ibilẹ Guusu Akure lasiko iṣejọba gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, oloogbe Olusegun Agagu.

Ọdun 2019 ni wọn tun dibo yan Expensive lati ṣoju ẹkun Guusu ati Ariwa Akure nile aṣoju-ṣofin labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ọpọ awọn awọn ololufẹ rẹ, to fi mọ ẹbi, ọrẹ atawọn oloṣelu bii tirẹ lo ti bẹrẹ si n sẹdaro iku oloogbe ọhun.

Ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.