Orí kó ọmọ ọdún mẹ́ta tí wọ́n gbé sọnù sínú gọ́ọ́tà ní Ondo yọ lọ́wọ́ ikú

Wọn ti doola ọmọbinrin, ọmọ ọdun mẹta kan ninu gọọta kan nitosi Fasiti imọ Iṣegun oyinbo to wa ni ipinlẹ Ondo.

Ọmọ kekere naa ti wọn ti sọ orukọ rẹ ni Esther bayii, ni alaanu Samaria kan ri ninu gọọta naa ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun 2021, ni agbegbe Ayeyemi Old Garage nilu Ondo.

Iroyin sọ pe niṣe ni wọn de ọmọ naa ni ọwọ ati ẹsẹ si inu apo, ki wọn o to o gbe si inu gọọta naa ti wọn n da ilẹ si.

Ọga Agba ileewosan ikọṣẹ iṣegun UNIMEDTH, Dokita Oluwole Ige, sọ ni ọjọ Ẹti pe ọmọ naa ti daku ki wọn o to o gbe de ileewosan, ṣugbọn o pada ji saye.

O ṣalaye pe ni kia ti alaanu naa gbe e de ileewosan ni wọn da oriṣiriṣi itọju pajawiri bo o nitori pe "o ti daku, ti ara rẹ si kun fun otutu, pẹlu okun ti wọn fi de e ni ọwọ ati ẹsẹ."

Bakan naa lo sọ pe wọn ti gbe ọmọ naa fun ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n mojuto iru awọn nkan bẹẹ nijọba ibilẹ Gusu Ondo, lati tẹsiwaju ninu amojuto ọmọ naa.